Manchester City vs Chelsea:Manchester City pàdí ọrẹ dà f'ogun ẹ̀yìn ja Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ami ayo meji si ẹyọkan ni Manchester City fi se agba fun ikọ Chelsea ninu Idije Premier League to n lọ lọwọ.
Aguero jade lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa n lọ lọwọ lẹyin ti o fi ara pa.
N'Golo Kante lo kọkọ gba bọọlu wọle fun Chelsea, ki o to di wi pe De Bruyne ti ikọ Man City da imọ mọ ru, ti o si gba bọọlu wọ inu awọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Riyad Mahrez lo da ẹgbọ si ara Chelsea, ti o si fi ami ayo keji si inu awọn ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi pari.
Kìnìhún Manchester City tó bú ramúramù, ó fẹ́ pa Chelsea jẹ ni?
Oni lonii jẹ, ẹ ni a bẹ lọwẹ lọrọ gbankọgbi ifẹsẹwọnsẹ Premier League toni.
Idije yii yoo waye ni papa iṣere Etihad laarin Manchester City ati ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nirọlẹ ọjọ Satide oni.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Manchester City
Abuku oloronbo ni Liverpool fi kan Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba kẹyin ninu idije Premier League, ami ayo mẹta sodo ni Liverpool fi ṣẹwọn leegun ẹyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Amọ, Chelsea fakọyọ ni ti wọn lẹyin ti fagba han Crystal Palace pẹlu ami ayo meji sodo.
Ẹwẹ, Frank Lampard to jẹ akọnimọọgba Chelsea funra rẹ ti figba kan gba bọọlu fun Man City lẹyin to kuro ni Chelsea.
Ni bayii, ipo kẹta ni Chelsea wa lori tabili Premier League, nigba ti Man City tẹle wọn ni ipo kẹrin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
- Ọmọ Nàìjíríà yarí lórí àbá láti mójútó ayélujára, ilé aṣòfin láwọn ń tẹ̀síwájú lórí ẹ̀
- Ọ̀nà kan ò wọjà fáwọn òṣèré tíátà, bí wọn ṣe ń ta ìpara ìbóra ni wọ́n ń ta aṣọ ẹbí
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Ẹ wo ìdí tí ẹ gbọdọ̀ fi gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ọmọ yín!
Ẹ gbẹ agbabọọlu Manchester City ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ni saa yii, nigba ti Chelsea kuna ninu meji.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ami ayo mẹfa sodo ni Chelsea jẹ lọwọ Man City nigba ti wọn koju ara wọn kẹyin ni papa iṣere Etihad.
Liverpool lo si wa loke tente, awọn nikan si ni ikọ agbabọọlu ti ko ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa bọọlu yii.