Ajínigbé ẹlẹ́ni mẹ́fà gbé ọkùnrin kan níwájú ilé rẹ̀ l’Ogun, bí àṣírí wọn ṣe tú rèé

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Awọn ikọ ajinigbe ẹlẹni mẹfa ji ọkunrin kan, Olorunsogo Oluwaseyi lọ niwaju ile rẹ ladugbo Soyooye nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.
Deede aago mẹjọ ku isẹju mẹẹdogun lọjọ Aje ni isẹlẹ naa waye lọjọ Aje ijẹta, tii se ọjọ Kejila osu Kejila ọdun 2022.
Ni kete ti wọn se ọsẹ naa tan, ni wọn gbe Oluwaseyi lọ sinu igbo nla kan lagbegbe Onigbedu to wa nijọba ibilẹ Ewekoro.
Awọn mọlẹbi ọkunrin yii si lo figbe ta lọ sileesẹ ọlọpaa lati fi isẹlẹ naa to wọn leti, amọ iwadi nipa isẹlẹ han sawọn ọlọpaa pe igbo Onigbedu ni awọn afurasi ajinigbe naa wa.
Atẹjade kan ti alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fisita lo sisọ loju isẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ti salaye, awọn osisẹ ọlọpaa, ti ọga ọlọpaa Sunday Opebiyi ko sodi atawọn ọdẹ ibilẹ, fijilante ati ọdọ lagbegba naa fi morile inu igbo naa lati doola Oluwaseyi.
Àlàyé rèé lórí bí ọwọ́ ṣe tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì náà:
Lasiko ti wọn fija pẹẹta pẹlu awọn ajinigbe naa, se ni wọn n dana ibọn ya laarin ara wọn, amọ apa awọn ikọ adoola ẹmi yii ka wọn, ti ọwọ si tẹ meji lara awọn afurasi ajinigbe naa.
Orukọ awọn afurasi ajinigbe ti ọwọ tẹ ni Ọjọru, ọjọ Kẹrinla osu Kejila ọdun 2022, eyiun ọjọ kẹta lẹyin ti isẹlẹ ijinigbe naa waye ni Umar Mohammed ati Aliyu Mohammed
Bakan naa ni ikọ alaabo naa doola ẹmi Olorunsogo Oluwaseyi lọwọ awọn eeyan to ji i gbe .
Lara awọn eroja ti wọn ka mọ awọn afurasi ajinigbe naa lọwọ ni ibọn sakabula ti ọta ibọn wa ninu rẹ, apo kan to jẹ ti ẹni ti wọn ji gbe pẹle awọn asọ kan.
Kọmisana ọlọpaa ni Ogun sọrọ lori isẹlẹ ijinigbe naa
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii, Kọmisana fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole, wa gboriyin fawọn osisẹ rẹ atawọn araalu fun isẹ takuntakun ti wọn se lati doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe naa.
O wa pasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi ajinigbe mejeeji naa lọ si ẹka agbofinro to n gbogun ti iwa ijinigbe labẹ ileesẹ ọlọpaa fun iwadi to ye kooro lori isẹlẹ naa.
Bankole tun pasẹ pe kawọn ọlọpaa bẹrẹ si ni finmu finlẹ lati se awari awọn afurasi mẹrin yoku to ti na papa bora , ki ọwọ le tẹ wọn lati wa fi imu kata ofin lori iwa ti wọn hu naa.
'À ń wá àwọn janduku tó yọ ojú ọmọ ọdún méjìlá yìí'

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Baunchi
Awọn janduku meji kan ti ṣekọlu si agbegbe Kafin Madaki ni ijọba ibilẹ Ganjuwa nipinlẹ Bauchi, ti wọn si yọ oju ọmọ ọdun mejila akẹẹkọ kan.
Ọmọ ọhun ni orukọ n jẹ, Najib Hussaini, to si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kano. Wọn ni o wa si Kafin Madaki nipinlẹ Bauchi, lati kọ imọ nipa kurani.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, Ahmed Wakil fi idi isẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Isẹgun.
O ni kọmisọna ileeṣẹ ọlọpaa, Aminu Alhassan ti palasẹ pe iwadii bẹrẹ lori isẹlẹ ọhun, ki wọn si wa awọn ọdaran naa ri .
Wakil ṣalaye pe, “Najib Hussaini, ẹni to n kọ ẹkọ nipa imọ Kurani ni Kafin Madaki ni ko ti pe ọdun kan to se si ipinlẹ nigba ti awọn janduku naa ṣekọlu si dede ago meji oorun ni ọjọ kẹsan an, oṣu kejila ni Unguwar Yamma, ibi to ko jina si ile ẹkọ rẹ.
“Nnkan ti a gbọ nipe awọn janduku meji, wa si agbegbe naa pẹlu ọkada, ti wọn si pe Hussaini lati ba wọn pe ọmọbinrin kan.
Wọn gbe e si ori ọkada wọn, ti wọn si m'orile agbegbe kan to dake niluu naa.
“Wọn duro si ibẹ, ti wọn si yọ ọkan lara oju ọmọ naa, wọn fi i silẹ ni agbara ẹjẹ.
“Ọmọ yii gbinyanju lati rin jade, ti awọn eeyan kan si ran lọwọ pada si ilu naa.”
















