Mọ̀ nípa tọkọtaya tó bímọ mẹ́sàn-án ní ẹ̀ẹ̀kan náà

Aworan

Oríṣun àwòrán, SALOUM ARBY

Gẹgẹ bii gbogbo lọkọlaya to n bimọ, Abdelkader Arby ati iyawo rẹ naa ni erongba ṣugbọn nigba ti awọn ọmọ yii de si aye, o ka wọn laya.

Halima Cisse, ẹni ọdun Mẹrindinlọgbọn, to jẹ iyawo Abdelkader bi awọn ọmọ mẹsan-an ọhun ni ẹẹkan naa lọjọ Kẹrin, Osu Karun-un ọdun 2020 ni orilẹede Morocco.

Ohun iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo agbaye nigba ti awọn tọkọtaya naa kede aṣeyori wọn, koda ajọ agbaye World Guinesss record fun awọn ọmọ naa ni ami ẹyẹ.

Nigba to ba ileeṣẹ BBC News sọrọ, Abdelkader Arby ni gbogbo awọn ọmọ ọhun lo wa ni alaafia lẹyin ti wọn pe ọdun kan.

“Awọn kan ti n rin bayii laarin wọn, awọn yooku si n ra nilẹ. Koda iya wọn wa ni alaafia.

“Ko rọrun rara ṣugbọn inu wa dun, tin nnkan ba safẹra, ti a ba ti woju awọn ọmọ naa, alaafia maa de pada.”

Awọn ọmọ ọhun, ọkunrin marun un ati obinrin mẹta. Orukọ awọn ọkunrin ni, Mohammed VI, Oumar, Elhadji, Bah, ti awọn obinrin si n jẹ Kadidia, Fatouma, Hawa, Adama and Oumou.

Baba ọmọ naa ni gbogbo awọn ọmọ yii lo ni ẹbun ti Ọlọrun fi jiiki wọn.

A ti ko awọn ọmọ pada si ilu abinibi wọn lorilẹede Mali

Baba wọn ni awọn ti pada si orilẹede Mali, to jẹ ilu abinibi awọn ọmọ naa.

Awọn ọmọ yii pẹlu awọn obi wọn ti de si papakọ ofurufu orilẹede Mali, ti ogunlọgọ awọn eeyan pẹlu Minisita fun eto ilera, Diéminatou Sangaré ni Bamako wa ki wọn kaabọ.

Arby dupẹ lọwọ awọn ijọba fun iranlọwọ ti wọn ṣe fun oun ati mọlẹbi.

O ni ijọba lo ṣe gbogbo eto lati tọju iya ati awọn ọmọ naa lorilẹede Morocco.

“Gbogbo awọn eeyan lo fẹ ri awọn ọmọ yii, ti inu wa si dun pupọ.”

Arby rọ awọn tọkọtaya to nreti ọmọ pe Ọlọrun yoo gba adura wọn, ti yoo si pese ọmọ fun wọn.