Ìjínigbé yóò di ohùn ìgbàgbé tí ń bá di Ààrẹ - Tinubu

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter | GovKaduna

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti ṣe ileri pe gbogbo ogun ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn ni yoo di ohun igbagbe ti oun ba di aarẹ orilẹede Naijiria ninu eto idibo lọdun 2023

Tinubu sọ eleyi nigba to gbe iponlogo ibo lọ si ipinlẹ Kaduna, to si fi ọkan awọn eeyan agbegbe naa balẹ pe, gbogbo isoro wọn ni yoo di ohun igbagbe.

“Gbogbo awọn to n fa wahala yii, awọn ajinigbe ti wọn da alaafia ipinlẹ yii lamu, mo n fi da yin loju pe, gbogbo rẹ ni yoo di ohun igbagbe.”

Kaduna jẹ ọkan lara ipìnlẹ kan lorilẹede Naijria to n koju idunkoko awọn ajinigbe, ti awọn alatilẹyin Tinubu si ni igbagbọ pe oun gan ni yoo yọ awọn kuro ninu gbogbo laasigbo ti ipinlẹ naa wa, paapa julọ ọrọ awọn ajinigbe.

Tinubu wa kan sara si gomina ipinlẹ Kadana, Malam Nasir El-Rufai fun isẹ takuntakun to ti ṣe lati igba to de si isẹjọba lọdun 2015.

O ni ipa ti El-Rufia ko ninu didaabo bo awọn eeyan ipinlẹ naa ni ko ṣee fi ọwọ rọ sẹyin rara.

Tinubu ni “isẹ nla ti El-Rufia ṣe, ẹ wo ayika ipinlẹ Kaduna bi o sẹ mọ tonitoni."