Olùdíje tó ń bẹ aráàlú fún ibo kò yẹ kó fara pamọ́ fún ìbéèrè - Bode George sí Tinubu

Bola Tinubu ati Bode George

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Oloye ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, Bode George ti tun fi oko ọrọ ranṣẹ si oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bola Tinubu.

Eyi n waye latari fa ki n fa to suyọ laarin rẹ atai ileeṣẹ amohunmaworan Arise TV to pe e wa sibi ipade itagbangba amọ ti Tinubu kọ pe oun ko ni laye foju han nibẹ.

Bí ọrọ naa ṣe kọkọ bẹrẹ, awọn igun APC ko fara ya rara, wọn ṣalaye pe awọn alakalẹ eto ti wa nilẹ fun ọjọ ti ileeṣẹ mohunmaworan naa fẹ ṣe itakurọsọ ti Tinubu ko si ni si nile amọ kete ti iroyin bẹrẹ si ni jade lati ẹka oju opo iwe iroyin kika wọn pe Tinubu n tẹ ẹtọ awọn araalu loju mọlẹ ni, eyi lo mu ki awọn agbẹnusọ fun Tinubu naa gbe ọrọ ọhun kari ti o si ti di ranto laarin wọn bayii.

Ẹwẹ, Oloye Bode George ti ileeṣẹ amohunmaworan naa pe lati fesi ko mu u kere rara.

O ni bii wiwu itan jade loun yoo fi bẹrẹ ọrọ Tinubu to si kẹnu bọ ọrọ to ni iru gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ yii ko ṣẹlẹ ri laye atijọ.

“Emi gan ti fara kasaa awọn atẹjade ti ko ja mọ nnkankan latọwọ Bayo Onanuga ati Dele nigba pipẹ sẹyin,nigba ti mo wa ri eyi to n ṣẹlẹ bayii, mo kan sọ fun ara mi pe oniṣẹ ara l’Ọlọrun Ọba ti ọrọ́ ti wa n pada yi le awọn naa lori bayii.

Bode ni awọn araalu nilo ilanilọyẹ torinaa, ko yẹ ki ẹnikẹni maa sọ́ pe “ma kan ni mi, tori araalu fẹ mọ ẹ, iwọ́ to n bẹ wọn pe ki wọ́n nifẹ ninu rẹ ki wọn si dibo fun ẹ, bawo wa ni wọn a ṣe mọ pe lootọ ni.”

"Wọn ti fitina emi naa laye igba ti mo jẹ gomina lasiko ijọba ologun"

Bode George

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bode George ni oun ranti igba ti oun naa n kuro gẹgẹ bii gomina lasiko ijọba ologun nipinlẹ Ondo, wọn kon ina ọrọ bo oun tori wọn mọ pe oun ṣi wa ninu ijọba.

“Emi o ri nkankan ti ileeṣẹ iroyin yii sọ to buru. Niwọn igba too ba ti pinu pe o fẹ gba ipo ijọba, ko gbudọ si kọlọfọfin kankan to n fi nkan pamọ si tori wọn gbudọ gbagbọ pe ni ọpọlọpọ ọdun sii, awọn ṣi lee fi ọkan tan ẹ.”

Oloye Bode George naa ni ọpọlọpọ igba ni APC naa ti ju oko ọrọ si ẹgbẹ oṣelu oun ti wọn si pe oun fun alaye.

O fi kun un pe bi wọn ba wa kaa si ikọlu to da eeyan kan sọtọ, wọn lee gba ọdọ awọn adajọ lọ.

Ṣe lootọ ni pe APC lẹbọ lẹru ni Tinubu ṣe n sa?

“Ohun ti mo fẹ sọ ni pe fun apẹrẹ, ibo kanṣoṣo ni mo ni , mo si gbudọ mọ ta lo koju osuwọn ju ninu ẹyin bii mẹrin tẹ n du ipo.

“Ki ni ibẹrẹ rẹ, ki lo ti ṣe ri, ṣe ile ẹkọ A lo lọ ni abi ti B, ipo wo lo gbe jade, awọn wo lẹ jọ kawe, bawo la ṣe le gba ọ gbọ...”

Bode George gbogbo ibeere eleyi ko pọ ju awọ́n nnkan to yẹ ki araalu mọ ni lọ nipa ẹni to ba fẹ di aarẹ tori atukọ to dara ju leeyan nilo lati gbe ilu yii de isalẹ Eko.

Iru eeyan wo ni Bode Geroge ni Tinubu jẹ?

Oloye Bode George ni ni toun, ọmọ Eko pọnbele ni oun ti oun si ṣe oun gbogbo ni Eko.

“Amọ emi mọ daju daju pe Bola kii ṣe ọmọ Eko. Ẹ lee ni mo sọ bẹẹ titi ayeraye. Mo ti lọ si ilu Tinubu, mo lọ ile ẹkọ rẹ to lọ koda eeyan kan ṣi wa ninu ẹgbẹ wa to jẹ onipele to kere si ti Tinubu to si sọ gbogbo ẹ fun wa.”

O ni bi Tinubu ba wa ni Isale Eko loun ti dagba, ko wa sọ ile ẹkọ to lọ nibẹ.