Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Crypto, FTX kó sí gbaga ọlọ́pàá lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ náà lulẹ̀

FTX founder Sam Bankman-Fried

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oludasilẹ ileeṣẹ Cryptocurency, FTX, Sam Bankman-Fried ti ko si gbaga ọlọpaa lorilẹ-ede The Bahamas lẹyin ti ileeṣẹ naa lulẹ.

Adajọ agba orilẹ-ede naa, to fi iroyin ọhun lede sọ pe oni gaan ni ọkunrin naa yoo foju ba ile ẹjọ nilu Nassau, to jẹ olu ilu ilẹ The Bahamas.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Bankman-Fried, to jẹ ẹni Ọgbọn ọdun hu iwa ọdaran to rọ mọ ṣiṣe owo kumọkumọ nilẹ Amẹrika ati The Bahamas lo jẹ ki awọn mu u.

Oṣu to kọja ni ileeṣẹ FTX kede nilẹ Amẹrika pe oun ti ko si oko gbese, ti ko si lee san owo fun awọn onibara rẹ mọ.

Gẹgẹ bii iwe to wa nile ẹjọ, iye owo ti FTX jẹ awọn onibara rẹ aadọta akọkọ ti owo wọn pọ ju lakata rẹ to $3.1b.

A ko le sọ iye eeyan ti owo wọn wa lakata ileeṣẹ idokowo naa ti yoo lanfani lati gba owo wọn pada.

FTX fun awọn onibara rẹ lanfani lati dokowo pẹlu ọna ati parọ owo si Crypto bii Bitcoin.

Awọn kan tilẹ ti n fi Bankman-Fried we baba olowo Amẹrika, Waren Buffet ṣaaju ijamba yii nigba ti iye owo ti oun funra rẹ ni ti fẹ ẹ le ni biliọnu marundinlogun dọla.

Ọpọ eeyan lo ti da mọ ni Washington gẹgẹ bii ẹni to maa n gbe owo kalẹ fun eto oṣelu, paapaa fun awọn oloṣelu to n ṣatilẹyin fun Crypto.

Afurasi naa yoo ṣi wa ni atimọle Bahamas bayii titi di igba ti wọn fi ṣe igbẹjọ lati gbe lọ silẹ Amẹrika.

Ọdun 2019 ni Bankman-Fried da ileeṣẹ FTX.COM silẹ, toun ti Gary Wang, to jẹ oṣiṣẹ Wall Street ati Google tẹlẹ.

Amọ ileeṣẹ ọhun wọ oko gbese lẹyin ti awọn onibara rẹ gba owo ti iye rẹ to biliọnu mẹfa dọla jade lakata rẹ laarin ọjọ mẹta pere.