Tinubu yóò fìdí Peter Obi lulẹ ní awọn ilẹ̀ Yorùbá torí Obi kéré sí Tinubu nínú Òṣèlú - Bayo Onanuga

aworan

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/TWITTER

Adari eto ipolongo ṣipo aarẹ fun Bola Ahmed Tinubu Bayo Onanuga ni adura ti Olubadan ti Ilẹ Ibadan Ọba Lekan Balogun ṣe fun oludije ṣipo aarẹ labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu Labour Peter Obi ni Ibadan laipẹ yii kọ ni yoo jẹ ki awọn ọmọ Yoruba dibo yan an gẹgẹ bi aarẹ orilẹede yii ninu eto idibo ọdun 2023.

Ṣaaju aworan kan ti wa lori ẹrọ ayelujara nibiti agbẹnusọ fun Kabiyesi Ọba Lekan Balogun ti gbadura fun Peter Obi ti o si sọọ pe yoo wọle gẹgẹ aarẹ orilẹede yii.

Peter Obi nigbati o ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu Olubadan ni, adura ti Olubadan gba fun oun ti to,Obi ninu gbogbo awọn ti wọn baa ohun du ipo aarẹ ko si ẹniti ọka ju oṣuwọn .

Bayo Onanuga ni gbogbo ilẹ Yoruba lo wa lẹyin Bola Ahmed Tinubu ti o si ni awawi lasan ni oludije ṣipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu LP Peter Obi n ṣe.

aworan

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/TWITTER

O ni gbogbo akọsilẹ eto idibo ni ilẹ Yoruba lati ọdun 1979 titi di akoko yii fihan pe ọmọ ẹni ko ni ṣe'di bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran ni ile Yoruba ma un se lakoko ẹto idibo.

Bayo ni igi imu jina s'ori bẹẹ gẹgẹ ni Tinubu kii ṣe ẹgbẹ Peter Obi ninu eto oṣelu nitori nigbati o jẹ gomina ipinlẹ Eko gbogbo aṣeyori Bola Tinubu lo ṣee fojuri, ati wi pe Tinubu ni imọ ju Peter Obi lọ.

O ni ko si ibẹru rara nitori wipe ti o ba di ọjọ idibo Asiwaju Bola Tinubu ni yoo jawe olubori.

Adari eto ipolongo fun Bola Tinubu ni Peter Obi ati Bola Tinubu ti jẹ Gomina ni mi ipinlẹ rẹ ṣugbọn ko si ẹni ti yoo de ilu Eko ti ko ni mọ wipe Tinubu ṣe iṣe ribiribi ni ipinlẹ naa pẹlu bi awọn agbegbe titun ti bẹrẹ si ni gboro sii ni ilu Eko.