Coronavirus: Ìjọba ní kò sí ìrìn-àjò sílẹ̀ òkèrè mọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari
Lati akoko yii lọ, oṣiṣẹ ijọba kankan ko gbọdọ riinrin ajo lọ si ile okere mọ, ijọba apapọ lo kede ọrọ nitori ajakalẹ arun coronavirus to tan kalẹ kaakiri agbaye.
Eyi ni igbesẹ igbimọ ti ijọba fi lọlẹ lori itankalẹ arun Covid-19 lẹyin ipade idankọkọ ti wọn ṣe niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Akọwe ijọba apapa to tun jẹ akọwe igbimọ naa, Boss Mustapha ṣalaye fawọn akọroyin pe ijọba ti wọgile gbogbo irin-ajo to ti buwọlu tẹlẹ fawọn oṣiṣẹ ijọba.
- Ààrẹ Buhari sún eré ìdárayá àpapọ̀ Edo 2020 síwájú
- Àwọn ọmọ Ilé Igbimọ Asofin àgbà ti fáríga nítori Coronavirus
- Ìjọba Somalia gbẹ́sẹ̀ lé ìrìn àjò òkè òkun lẹ́yìn tí Coronavirus báwọn lálejò
- Ọmọ Nàìjíríà kan ti ní àrùn Coronavirus nípìnlẹ̀ Eko
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Bí Fayemi bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀, àwọn oníbáwí rẹ̀ wà l'Ekiti-Peter Fatomilọla
Ọgbẹni Mustapha ṣalaye pe ijọba ko fẹ ki arun naa tan kalẹ ju eeyan mẹta to ti lugbadi rẹ lọ lorilẹede Naijiria.
Igbimọ naa rọ awọn ọmọ Naijiria pẹlu lati maa rinrin ajo lọ si lọ si oke okun lasiko yii yala fun iṣowo tabi isinmin papaajulọ si awọn orilẹede ti arun coronavirus ti n ṣọṣẹ lọwọlọwọ.
Igbimọ naa ni awọn orilẹede bi China, Iran, South Korea, Germany, Italy, United States, United Kingdom, Switzerland, Norway, Netherlands, Spain, France ati Japan ko ṣee rinrin ajo lọ lasiko yii nitori coronavirus.
Bakan naa ni igbimọ ọhun awọn ọmọ Naijiria to n bọ lati ilẹ okere wi pe ki wọn ya ara wọn sọtọ fun ọjọ mẹrinla nile wọn kete ti wọn ba ti wọ Naijiria pada.
Lọjọ Iṣẹgun ni Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l'Abuja ké si ìjọba àpapọ pe ko fi sínú ero rẹ láti fi ofin de àwọn arinrin ajò ti kìí ṣe ọmọ Naijíríà láti àwọn orilẹ̀-èdè ti àrun (COVID-19) náà n bá fíra láti ma wọ Naijiria mọ́.












