Coronavirus: Ọmọ ilẹ̀ Italy tó kó Coronavirus wọ Naijiria kò ní àrùn náà mọ́

Eeyan kan wọ iboju idaabobo lọwọ arun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ayẹwo ti fi han pe ọmọ orilẹde Italy to ko arun Coronavirus wọn Naijiria ko ni arun naa mọ.

Ṣaaju ni ọkunrin ọhun to wa si Naijiria lati ilu Milan lọjọ kẹrinlelogun, Oṣu Keji ọdun yii ti n gba itọju nile iwosan ijọba to wa ni yaba, nilu Eko.

Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi sọ fun awọn akọroyin nibi ifọrọwerọ kan pe ẹni ọdun mẹrinlelogoji naa ko ni arun ọhun lara mọ.

Abayomi tẹsiwaju pe wọn yoo ṣe ayẹwo mii fun ọkunrin naa, ti esi rẹ ba wa bakan naa, wọn yoo da silẹ ko ma lọ ile rẹ layọ ati alafia.

O ni "Ọkunrin naa ko ni arun Coronavirus lara mọ, ṣugbọn idi ti a ṣi fi da duro ni pe a fẹ ṣe ayẹwo miran fun ki a to fi silẹ ko maa lọ ile rẹ."

Ọmọ ilẹ Italy naa wọ sile itura kan to sunmọ papakọ ofurufu ilu Eko ni kete to gunlẹ si Naijiria, ko to lọ si ipinlẹ Ogun fun iṣẹ aje.

Ọjọ kẹta to de si Naijiria ti lo ṣaisan rampẹ, ti ayẹwo si fi han pe arun Coronavirus lo n ba finra.

Àkọlé fídíò, Làá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus

Coronavirus: Èèyàn mẹ́rin míràn ní àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Èkó

Igo awo fun coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹẹdẹgbeje (1300) awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun.

Kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo ṣalaye eyi lẹyin to kede eeyan mẹrin miran pẹlu arun Coronavirus bayii.

Eyii ti mu ki apapọ awọn eeyan to ni arun naa ni Naijiria pe mejila bayii.

Ọjọgbọn Abayọmi ni ayẹwo mọkandinlogun ni wọn ṣe lori awọn ti wọn funrasi pe wọn ni aarun naa atawọn eeyan to ni nnkan pọ pẹlu awọn awọn marun ti wọn kede pe wọn ni arun naa lọjọru.

Mẹrin ninu ayẹwo ọhun lo ja si tootọ.

Aworan ọwọ fifọ

O ni akọkọ ninu wọn ni ọmọbinrin ọmọ orilẹede Naijiria kan to wọ orilẹede Naijiria lati orilẹede France pẹlu baluu ilẹ Turkey kan lọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun 2020.

O fi kun pe ẹni keji ni ọmọkunrin kan ti ọjọ ori rẹ ti le ni aadọta ti ko rinrinajo lọ si ibikibi.

Ẹnikẹta ni arakunrin miran to wọ orilẹede Naijiria ni ọjọ kẹtala oṣu kẹta lati ilu Frankfurt lorilẹede Germany.

O ni ẹẹdẹgbeje awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun.