Nathaniel Samuel: Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lórí afurasí tó gbé ado olóró wọ ilé ìjọsìn Winners

Oríṣun àwòrán, Google
Ọwọ palaba arakunrin kan ti wọn fura si pe o fẹ yin ado oloro ni ile ijọsin Living Faith Church ni adugbo Sabo ni Kaduna ti segi.
Awọn aworan ta ri loju opo ayelujara niṣe ni arakunrin naa mu nkan ti o o jọ ado oloro atọwọda lọwọ ti awọn ọlọpaa si rọ yika rẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kaduna Yakubu Sabo, fidi ọrọ naa mulẹ ti o si ni iwaadi ti bẹrẹ lati mọ ibi tarakunrin naa ti wa ati ero rẹ.
''A mu arakunrin kan ti orukọ rẹ njẹ Nathaniel Samuel ninu ile ijọsin Living Faith lasiko ijọsin pẹlu awọn ohun ta furasi pe o jẹ ado oloro atọwọda''
Nigba ti akọroyin wa bere lọwọ rẹ́ẹ boya ọmọ inu ile ijọsin naa nii ṣe, o ni awọn ko ti le sọ ati pe iwaadi ṣi ntẹsiwaju lati mọ boya ara ita ni tabi ọmọ ile ijọsin naa
Gẹgẹ bi ohun ta ri ninu awọn fọnran fidio to wa loju opo Facebook,a ri arakunrin naa to joko sinu ọkọ pẹlu awọn ọlọpaa.








