Streatham: Àwọn ọlọ́pàá pa afurasí tó gún èèyàn lọ́bẹ pa ní London

Oríṣun àwòrán, DAN SMITH
Wọn ti yinbọn pa arakunrin afurasi kan ninu iṣẹlẹ kan eleyi to jọ igbesunmọmi ni Guusu ilu London
Ileeṣẹ ọlọpaa lo fi ikede yi sita lọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, awọn ọlọpaa ni o jọ pe awọn eeyan meji ti farapa ninu igunilọbẹ ni opopona Streatham
Awọn oṣojumikoro lojuopo Twitter ni awọn gbọ iro ibọn ni nkan bi ago meji ọsan lọjọ Aiku ti awọn dokita si n tọju awọn to farapa.
Ileeṣẹ ọkọ to n tọju alaisan ni London ni awọn oṣiṣẹ awọn wa ni ṣẹpẹ ti wọn si ti n tọju awọn eeyan kan.
Ninu ọrọ ti ẹnikan fi si oju opo Twitter o ni 'Nkan n ṣẹlẹ ni opopona Streatham. Awọn ọlọpaa ti gbegi di oju ọna'
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọmọ ọdun mọkandinlogun kan Gulled Bulhan ni ohun ri bi wọn ṣe yinbọn pa arakunrin naa niwaju ile itaja ogun Boots Pharmacy.
''Mo n sọda loju ọna ni ki n to ṣadede ri ọlọpaa kan ti ko wọ aṣọ to n le arakunrin kan ti o mu ada lọwọ ti o si so awọn agolo kan mọ aya.
Lẹyin igba naa oni ''wọn yinbọn pa arakunrin naa.Mo gbọ iro ibọn lẹẹmẹta ti mo si ṣare wọ ile ikawe ki awọn ọkọ ọlọpaa to wa bẹrẹ si ni sare kọja''












