Big Brother Naija Lockdown season: Ṣé èèwọ̀ ni kí Vee fọ pátá olólùfẹ rẹ̀ ni?

Neo tó n fọ pátá Vee, ẹ wo ohun táwọn olólùfẹ́ bó ṣe n lọ nílé ẹlẹ́gbọ́n àgbà BB Naija n sọ

Oríṣun àwòrán, BBNaija

Awọn ololufẹ eto agbelewo Big Brother Naijiria to n lọ lọwọ ti tu sita lori ayelujara lati sọrọ takorawọn lori pe boya wọn lee fọ pata ololufẹ wọn bii ti Neo, akopa eto BBNaija to n fọ pata akopa ẹlẹgbẹ rẹ, Vee lori eto.

Sebi, ọrọ ifẹ bi adanwo ni lo difa fun bi o ṣe ba Nengi to jẹ olori ile bayi nile ẹlẹgbọn agba lojiji nigba to gbọ pe Neo n fọ pata Vee.

Neo ati Vee nikan ni ololufẹ meji ti ida Big Brother ko ti bẹ irẹpọ wọn si meji pe ki eeyan kan kọri sile, wọn ti wa yege lati wa lara awọn marun to kẹyin nile ẹlẹgbọn agba bayi lẹyin ti ori yọ wọn pe wọn o le wọn lọ sile lọsẹ to kọja.

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Ninu fidio tawọn eeyan rọra ge lara eto naa to gba ori ayelujara kan, ẹrọ ayaworan ṣafihan Neo to n fọ aṣọ nigbati Nengi ati Vee n wo o.

Ọrọ ko ba tilẹ ma han sita bi ko ṣe igba ti Vee sọ pe "Ololufẹ mi, ko ma si pata kan ninu aṣọ, ọrọ naa ba ṣe oju Nengi wara wara to ya a lẹnu.

Nengi kọkọ ka a sara ko sọrọ, nigba to ya lo ba fọhun pe "Neo, ṣe pe o tun n fọ pataaa, haaa!Vee naa ba da a lohun pe "Neo mi gan mọ pe onimọtoto ni".

Nengi wa sọ fun Neo pe o yẹ ẹ gan o.Iṣẹlẹ yii ti n mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria fọn ti wọn si ti n fesi.

Awọn esi wọn n pa ni lẹrin jọjọ, ṣe ẹ mọ pe bi igbati o n ṣẹlẹ lẹyinkunle wọn lawọn to n wo eto naa ṣe maa n sọrọ...@Zoeman ni "aṣe o tilẹ tun lẹnu lati sọ pe o ku pata kan, ara ni yoo san pa pata kan ọhun".

O ni arifin Neo ma pọ o.@Iamemzy ni "Jeeesu, Neo n fọ pata, kilode tawọn ọkunrin maa n doju ti mi bayii lẹnu ọjọ mẹta"...@emmanueladem naa sọ loju opo Twitter pe o yẹ Vee gan o pe koda Ozo gan ko ṣe to bẹẹ.

SC Genotype: Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ààrùn Sickle Cell 'SC' tí Laycon BBNaija ní

LayhconOriṣiriṣi ọrọ ni awọn ololufẹ eto ori amohunmaworan BBNaija season 5 ti n sọ lẹyin ti ọkan lara awọn olukopa to de ipele asekagba, Laycon sọ pe SC ni jẹnotaipu oun.

Iroyin sọ pe alẹ ọjọ Aje ni Laycon sọ fun awọn akẹẹgbẹ rẹ lasiko ti wọn n jiroro.

Sugbọn kii gan-an ni iyatọ to wa laarin aisan aromọleegun 'Sickle Cell' SS ati SC?

Ọna kan naa ti eeyan n gba jogun eroja SS, ni ẹni to ba ni SC n gba jogun ti wọn naa lati ara awọn obi wọn.

Awọn kan wa to ni eroja SC yii to jẹ pe aisan sickle cell ma n jẹ jade ni ara wọn.

Eroja ara Hemoglobin SC yii ni aarun aromọleegun sickle cell keji to wọpọ julọ.

O si ma n waye ti ọmọ ba jogun eroja Hb C lara obi kan, ati Hb S lara òbí keji.

Botilẹjẹ pe àpẹẹrẹ kan naa ni ẹni to ni SC ati SS ma n ni, ipa ti SC ko fi bẹ ẹ l'agbara pupọ.

Onimọ eto ilera kan ṣalaye pe lootọ ni aridaju ko fi bẹ ẹ si lori bi ẹni to ba ni SC yoo ṣe pẹ laye to, o ni o yẹ ki ẹmi wọn ko gùn, ti wọn ba mojuto ilera wọn daadaa.

Bakan naa lo sọ pe àṣìṣe nla ni ti ẹni to jẹ SC ba fẹ SS tabi SS ni ọkọ tabi iyawo.

Ẹ̀jẹ̀ ara 'red blood cells, RBCs' ni aarun aromọleegun sickle cell ma n ba a ja, eyi ti wọn n pe ni sickle cell anaemia. Ó si jẹ ajogunba lati ara obi si ọmọ.

Fun ẹni ti ara rẹ ba dape, ni ṣe lo yẹ ki eroja red blood cell naa ri roboto, eyi to ma n mu ki o rọrun fun lati gba inu ọ̀pá to n gbe ẹjẹ.

Sugbọn fun ẹni to ba ni aarun aromọleegun sickle cell, eyi ko ribẹ. Ni ṣe ni ti wọn ma n da bi akọ́rọ́, ti wọn fi n kore ni oko.

Eyi si ma n mu ki wọn o di ọna ti ẹ̀jẹ̀ n gba lọ sinu àwọn ẹ̀yà ara. O si le fa irora.

Àwọn ami ti aarun aromọleegun sickle cell ma n fihan

Nigba ti ọmọ ba wa ni kekere, ni ami aarun sickle cell ti ma n jade ni ara. O le jẹ lati ọmọ oṣu mẹrin, sugbọn kii saba kọja oṣu mẹfa.

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ni aarun yii, ami kan naa ni gbogbo wọn ni. Bi wọn ṣe l'agbara to lo yatọ.

Diẹ lara wọn ni :

Ki aarẹ ko ma a mu ara, aito ẹjẹ ninu ara, iba apọnju 'jaundice', ọwọ ati ẹsẹ ẹni naa yoo wu, yoo si fa irora.

Bakan naa ni orisirisi aarun yoo ma ṣe ẹni naa ni gbogbo igba

Àyà, ẹyin, apá ati ẹsẹ yoo ma dun ẹni naa.