ASUU strike: Ìdí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Nàìjíríà kìí tètè kẹ́kọ̀ọ́ parí

Awọn olukọ fasiti OAU

Oríṣun àwòrán, Emmanuel oloye

Àkọlé àwòrán, ASUU ṣalaye pe o di igba ti ijọba apapọ ba mu adehun to baa ṣe ṣẹ ki awọn to pada si ẹnu iṣẹ

Ọlamide Tẹjuoso ti n fojusun ibẹrẹ ọdun 2019.

O ti n reti lati di akẹkọọ gboye tuntun ko si bẹrẹ ikọṣẹ ti yoo maa gba owo ni ile iṣẹ iroyin kan.

Ṣugbọn dipo ki inu rẹ dun, inu akẹkọọ nipa imọ iroyin yii ko dun si iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn olukọni fasiti(ASUU) to n lọ lọwọ.

Awọn akẹkọọ fasiti to ṣe pe ijọba ipinlẹ lo n seto isuna wọn ko tii wọle ẹkọ pada nitori iyanṣẹlodi ẹgbẹ ASUU eyi to jale jako gbogbo orilẹede.

Ẹgbẹ naa fi ẹsun kan ijọba pe o kuna lati ṣe ohun ti wọn jọ fẹnu ko si latẹyin wa lori idagbasoke awọn ile ẹkọ giga.

Ami idanimọ ẹgbẹ́ ASUU

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Ajọ awọn oṣiṣẹ olukọ ile ẹkọ giga

Bakan naa, wọn ja fun ṣiṣe atunṣe awọn ohun elo to ti bajẹ, aito owona àti ẹsun pe wọn fẹ fi kun owo ile iwe.

Ẹgbẹ ASUU pẹlu ijọba apapọ ṣepade lọjọ aje nibi ti minisita fun ọ̀rọ̀ oṣiṣẹ, Chris Ngige sọ wi pe igun mejeeji ti fi adehun sọ̀kan. Pe, ijọba ti ṣe tan lati pese 15.5bn ($42m, £33m) fun awọn fasiti ti ijọba.

Aarẹ ẹgbẹ ASUU, Biodun Ogunyemi ni ohun aaṣe ṣi ku ki ẹgb to gba ati pe iyanṣlodi ko tii pari.

"O n mu irẹwẹsi ba ọkan, ni arabinrin Tejuoso wi, gẹgẹ bi akẹkọọ ipele to gbẹyin, mi o le rinrinajo kan to ṣe san an, mi o le ṣiṣẹ gidi tori a o mọ igba ti a o wọle pada.

"A o mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, nitori idibo ti sunmọ, wiwọle ninu oṣu keji, bakan meji ni. A o tilẹ mọ bi ọjọ waju ṣe ri fun wa.

Awọn akẹkọ fasiti Ibadan
Àkọlé àwòrán, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan dunnú, àwọn míràn fajúro si iyansẹlodi Asuu

Ẹwẹ, adari ẹgbẹ, Ọjọgbọn Oguyemi ti oun funra r ni ọm meji nile iwe giga fasiti ni iyanṣlodi naa wa lati da abo bo ile iwe naa ati ọjọ́ iwaju awọ̀n ọmọ wọn.

"A ti maa n sọ fun awọn akẹkọọ atawọn obi wọn pe tori wọn naa la ṣe n ṣe eyi." ni Ọjọgbọ Ogunyemi sọ.

A fẹ ki wọn gba iwee ẹri to ko ni niyii.

Ijọba naa ti gbe ọpọlọpọ owo silẹ lati san owo ti wọn n jẹ awọn olukọ.

O fẹrẹ jẹ pe ọdọọdun ni ASSU n gunle iyanṣẹlodi.

ui gate
Àkọlé àwòrán, ọ̀dọ́ ni agbara orilẹ-ede nibi ti eto ẹkọ ti ṣe koko

Ohun to ku ni lati ati ri adari lere ti yoo mọ riri eto ẹkọ si idagbasoke ọlọdani ninu orilẹede.

Lasiko idibo yii, ẹni to ba fẹ polongo ibo, ẹka yii lo yẹ ko wa.

Lati igba ti iyanṣẹlodi ti bẹrẹ, owo ori ẹrọ ayelujara lo n ṣe eyi to si wọpọ laarin awọn ọmọ.

Bakan naa, ọkan pataki lara awọn owo ori rọayelujara, Jobberman jẹ iṣẹ ọeọ awọn akẹkọọ kan nigba iyanṣẹlodi ASUU lọdun 2009.

Bi o tilẹ jẹ pe omidan Agu Uka n gbadun owo rẹ, o ni idamu nipa bi akoko iyanṣẹlodi naa ṣe n pa ẹkọ rẹ lara.

Nigba ti awọn akẹkọọ bii arabinrin Tejuoso ni ireti pe abajade ifọrọwerọ ijọba ati ASUU yoo ṣọmọ ire, bẹẹ naa ni ibanilọkan jẹ n wa pe bi wn ko ba wa wọrọk fi ṣada, iyanṣẹlodi yoo di baraku ninu igbe aye awọn akẹkọọ Naijiria.