Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Wọ́n kí ọwọ́ bọ̀ mí lójú ára, wọ́n fẹ́ fipá bá mi lòpọ̀ lójú títì, mi ò sì kí ń fi bò lórí ayélujára torí...

Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb

Wọ́n kí ọwọ́ bọ̀ mí lójú ára, wọ́n fẹ́ fipá bá mi lòpọ̀ lójú títì, mi ò sì kí ń fi bò lórí ayélujára torí...

Orukọ Kemi Olunloyo kii ṣe aimọ fun oloko gbogbo eeyan to ba n tẹle awọn oniroyin ori ayelujara daadaa tori o jẹ eekan laarin wọn.

O jẹ́ eeyan kan ti ẹnu kii ṣi lara rẹ nigba gbogbo tori awọn iroyin kanka kanka to maa n gbe jade. Eyi ko si tu irun kankan lara rẹ tori pe o ni oun mọ nkan ti oun n ṣe.

Lori ohun to ṣẹlẹ si Sunday Igboho, Olunloyo ni "Àwọn tó ní "passport" orílẹ̀èdè mìí, Igboho àti Kanu ló fẹ́ da Nàìjíríà rú, ẹ má tẹ̀lé wọn o".

Ọpọlọpọ ọdun ni Kemi Olunloyo ti lo ninu iṣẹ oniroyin aṣewadii to si ni nibayii, iṣẹ oniroyin asọ ero ẹni lo kan fun ohun tori o ti di ọga ninu iṣẹ naa to si ti fi le awọn ọdọ lọwọ lati tẹsiwaju.

Ni ọpọ igba o lee jẹ ẹni akọkọ ti yoo gbe iroyin nla kan jade amọ ti ọpọ eeyan yoo maa bu pe nibo lo ti rii ti wọn o ni gbaa gbọ, nigba miran awọn iroyin yii maa n pada jẹ ootọ ti omii yoo si ni itumọ ọtọ.

Kemi Omololu-Olunloyo jẹ ọmọ Naijiria to tun kawe nipa imọ iṣegun oyinbo, ẹka pipoogun amọ iṣẹ iroyin lo n ṣe titi di oni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ pẹlu BBC Yoruba, o fesi pe ọpọ igba ti oun ti ko sọwọ ofin nitori ohun ti wọn pe ni iroyin ofege tabi ibanilorukọ jẹ, kii ṣe pe oun kan ṣee amọ awọn to maa n baa wa iroyin ni ko ṣe gbogbo iṣẹ ọfintoto wọn daadaa ki wọn to jabọ fun oun.

Bakan naa, Kemi sọrọ o kunlẹ nipa igbe aye rẹ ati bi mọlẹbi rẹ ṣe kọọ silẹ ti oun naa ko si fẹ ni ohunkohun ṣe pẹlu wọn.

O tun mẹnu ba idi ti kii fii ṣẹnu ku sọrọ nipa bi awọn ọkunrin kan ṣe baa lopọ ti yoo maa sọọ lori ayelujara.

Ọrọ ija laarin oun ati gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara mii, Esther Aboderin ti ọpọ mọ si ESABOD ko gbẹyin.