Ṣáájú ni obìrin náà ti kọ́kọ́ di àwátì ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn kí àṣírí tó tú

Delta

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti wu oku obinrin ẹni ọdun mẹrindilogoji kan ti wọn sọ pe alabagbe ati ẹsọ ẹnu ọna rẹ ṣekupa ni ilu Asaba.

Obinrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Obiagelu Onakanse ni wọn sin sinu ile kan lagbegbe GRA ni ilu naa.

Ṣaaju ni obinrin ọhun ti kọkọ di awati ni nnkan bi ọsẹ meji ṣeyin ki asiri to tu pe awọn to sun mọ ọ lo dẹmi rẹ legbodo.

Iroyin ni apa ibi to ti farapa wa lori rẹ, bakan naa ni oju ibi ti wọn ṣa a ladaa ṣi wa lara rẹ lẹyin ti wọn wu oku rẹ tan.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, igbakeji kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ Delta, Faleye Olayele gboṣuba kare fun awọn agbofinro fun iṣẹ takuntakun ti wọn lori iṣẹlẹ naa.

Delta

Oríṣun àwòrán, others

O fi kun pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tuṣu de isalẹ ikoko gbogbo bi ọrọ naa ṣe ṣẹ.

Faleye ṣalaye pe afurasi ti wọn gbamu kọkọ sẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn o ko ọrọ rẹ jẹ ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.

igbakeji kọmiṣona ọlọpaa sọ siwaju si pe bi oloogbe naa ṣe dero ọrun ko ṣeyin oun.

O ni afurasi naa lo mu awọn agbofinro lọ ibi to sin oku obinran ọhun si lẹyin to gẹ ẹmi rẹ kuru.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu