Naijiria pe ọgọta ọdun:
1960-2020
Aato idasilẹ awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji nibamu pẹlu akoko ti wọn da wọn silẹ.

Lati sami ayẹyẹ ominira ọgọta ọdun orilẹede tawọn eeyan rẹ pọ julọ ni Afirika, a wọ inu itan lọ lati tọpasẹ bi wọn se pin aala ilẹ ati idasilẹ awọn ipinlẹ ni orilẹede yii, Naijiria.
Asopọ apa Ariwa ati Guusu ti aṣoju ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Sir Fredrick Lugard ṣe lọdun 1914 lo bi orilẹ-ede Naijiria. Iyawo Lugard to tun jẹ akọroyin, Lady Flora Louise Shaw lo sọ orilẹ-ede naa ni "Naijiria."

Gomina apapọ fun Naijiria, Ọlọla Fredrick Lugard ati aya rẹ, Ọlọla-binrin Flora Shaw Lugard
Gomina apapọ fun Naijiria, Ọlọla Fredrick Lugard ati aya rẹ, Ọlọla-binrin Flora Shaw Lugard
Naijiria pin si ẹkun mẹta tii ṣe: Ẹkun Ariwa, Ẹkun Iwọ oorun ati Ẹkun Ila oorun lẹyin iwe ofin tuntun ti aṣoju ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Arthur Richard ṣe lọdun 1949. Awọn ẹya Hausa ati Fulani lo pọju lẹkun Ariwa, Yoruba ni Iwọ oorun ati Igbo ni Ila oorun.

Olootu apapọ fun ijọba, Sir Abubakar Tafawa Balewa, Ahmadu Bello- Olootu ẹkun Ariwa Naijiria ati Ọmọwe Nnamdi Azikiwe, Gomina apapọ fun Naijiria bawọn peju sibi ayẹyẹ ominira Naijiria to waye ni ọjọ Kinni, pṣu Kẹwa dun 1960 nilu Eko.

Naijiria pin si ẹkun mẹrin lọdun 1963, pẹlu idasilẹ Ẹkun Aarin gbungbun iwọ-oorun .

Olootu ẹkun ariwa Naijiria, Ahmadu Bello, Oloye Obafemi Awolowo ti ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria ati Ọmọwe Nnamdi Azikiwe, aarẹ akọkọ ni orilẹede Naijiria laarin ọdun 1963 si 1966.
Olootu ẹkun ariwa Naijiria, Ahmadu Bello, Oloye Obafemi Awolowo ti ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria ati Ọmọwe Nnamdi Azikiwe, aarẹ akọkọ ni orilẹede Naijiria laarin ọdun 1963 si 1966.

Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ẹkun mẹta
Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ẹkun mẹta

Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ẹkun mẹrin
Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ẹkun mẹrin

Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mejila
Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mejila

Aworan Naijiria to n se afihan ipinlẹ mọkandinlogun
Aworan Naijiria to n se afihan ipinlẹ mọkandinlogun
Lẹyin ọdun meje, ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Karun ọdun1967 ni olori orile-ede Naijiria nigba naa, Ọgagun Yakubu Gowon pin Naijiria si ipinlẹ mejila lẹyin t'awọn ẹya kekekee n ṣaroye pe, awọn ẹya to pọ n jẹ gaba lawọn lori.

Ọgagun Yakubu Gowon, Olori ijọba ologun ati alakoso ikọ ọmọ ogun Naijiria 1966 si 1975
Ọgagun Yakubu Gowon, Olori ijọba ologun ati alakoso ikọ ọmọ ogun Naijiria 1966 si 1975
Gowon pin Ẹkun Ariwa tẹlẹ si mẹfa: Apa iwọ-oorun Ariwa, apa ila-oorun Ariwa, apa Aarin gbungbun Ariwa (tii ṣe ipinlẹ Kaduna), ipinlẹ Benue-Plateau ati ipinlẹ Kwara.
Ẹkun Iwọ oorun tẹlẹ di ipinlẹ meji: Ipinlẹ Iwọ oorun ati Ipinlẹ Eko.
Ẹkun aarin gbungbun iwọ oorun tẹlẹ di ipinlẹ Bendel, nigba ti
Ẹkun ila oorun tẹlẹ di ipinlẹ aarin gbungbun ila oorun, Ipinlẹ Rivers ati Cross River.
Lọjọ kẹta oṣu keji ọdun 1976, lẹyin iditẹ gbajọba to waye, Ọgagun Murtala Muhammed ṣe idasilẹ ipinlẹ tuntun meje mii: ipinlẹ Imo ati Anambra lati Inu ipinlẹ aarin gbungbun ila oorun.

Ọgagun Murtala Mohammed ni olori ijọba ologun kẹrin ni Naijiria laarin ọdun 1975 si 1976.
Ọgagun Murtala Mohammed ni olori ijọba ologun kẹrin ni Naijiria laarin ọdun 1975 si 1976.
Ipinlẹ ila oorun Ariwa pin si ipinlẹ Bauchi, Gongola, ati Ipinlẹ Bornu.
Ipinlẹ Benue-Plateau di ipinlẹ Plateau ati Benue.
Ipinlẹ Iwọ oorun pin si mẹta: ipinlẹ Ondo, Ogun, ati Ipinlẹ Oyo.
Ipinlẹ Iwọ oorun Ariwa pin si ipinlẹ Sokoto ati Niger. Eyi lo jẹ ki awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria di mọkandinlogun.
Bo tilẹ jẹ pe ọdun kan yii naa ni ijọba kede idasilẹ Abuja lati ipinlẹ aarin gbungbun Ariwa (Kaduna), ipinlẹ Benue-Plateau, ipinlẹ Kwara ati Ipinlẹ Iwọ oorun Ariwa (Ipinlẹ Niger).
Lọdun 1987, Ọgagun Ibrahim Babangida Kede idasilẹ ipinlẹ tuntun meji sii: Ipinlẹ Akwa Ibom ati Ipinlẹ Katsina, eyi to sọ gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria di mọkanlelogun.

Ọgagun Ibrahim Badamosi Babangida ni olori ijọba ologun laarin ọdun 1985 si 1993
Ọgagun Ibrahim Badamosi Babangida ni olori ijọba ologun laarin ọdun 1985 si 1993
Lọdun 1991 ni Babangida tun kede idasilẹ ipinlẹ mẹsan an mii: Ipinlẹ Abia, Enugu, Delta, Jigawa, Kebbi, Osun, Kogi, Taraba ati Ipinlẹ Yobe, ti awọn ipinlẹ ni Naijiria sí di ọgbọn.
Fun alaye síi, ninu ipinlẹ Cross River ni Akwa Ibom ti jade, ipinlẹ Katsina jade lati inu ipinlẹ Kaduna.
Adamawa ati Taraba jade lati inu ipinlẹ Gongola.
Enugu jade lati inu ipinlẹ Anambra, nigba ti Edo ati Delta jade lati inu ipinlẹ Bendel.
Ipinlẹ Yobe jade lati inu ipinlẹ Borno, Jigawa jade lati inu ipinlẹ Kano.
Kebbi jade lati inu Sokoto nigba ti Osun jade lati inu ipinlẹ Oyo.
Ipinlẹ Kogi jade lati inu ipinlẹ Kwara ati Benue.

Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mọkanlelogun
Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mọkanlelogun

Aworan Naijiria to n se afihan ipinlẹ ọgbọn
Aworan Naijiria to n se afihan ipinlẹ ọgbọn
Lẹyin ti asaaju ijọba Fidi hẹ, Oloye Ernest Shonekan kọwe fipo silẹ lọdun 1993, Olori ijọba ologun ni Naijiria, Ọgagun Sanni Abacha gba akoso ijọba.

Ọgagun Sani Abacha ni olori ijọba ologun Naijiria laarin ọdun 1993 si 1998
Ọgagun Sani Abacha ni olori ijọba ologun Naijiria laarin ọdun 1993 si 1998
Ni ọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 1996, Ọgagun Sani Abacha kede idasilẹ ipinlẹ tuntun mẹfa mii:
Ipinlẹ Ebonyi lati inu ipinlẹ Abia ati Enugu, ipinlẹ Bayelsa lati inu ipinlẹ Rivers, ipinlẹ Nasarawa lati inu ipinlẹ Plateau, Gombe lati inu Bauchi, Ekiti lati inu Ondo ati ipinlẹ Zamfara lati inu Sokoto.

Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu ilu ilẹ wa, Abuja
Aworan orilẹede Naijiria to se afihan ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu ilu ilẹ wa, Abuja
Lati ọjọ ti Naijiria ti gba ominira lọdun 1960, ijọba orile-ede yii ti pin ẹkun Ariwa ati Guusu s'awọn ẹkun ati Ipinlẹ mẹrindinlogoji.
Eyi ni irinajo bi oriṣiiriṣi ijọba ṣe pin Naijiria si awọn ipinlẹ to wa lonii lati ọdun 1960.
Naijiria ẹ ku ayẹyẹ ominira ọgọta ọdun!

Aworan lati ọwọ̀:
Lati ọwọ: Nkechi Ogbonna
Akọle lati ọwọ̀: Olaniyi Adebimpe
Ẹni to se agbekalẹ rẹ ni: Nkechi Ogbonna