Oyo Budget: Makinde ya ₦56.3 bílíọ̀nù sọ́tọ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ nínú àbá ètò ìṣúná ọdún 2021

Makinde

Oríṣun àwòrán, @Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makide, ti ṣagbekalẹ aba eto iṣuna ọdun 2021 ti iye rẹ le ni ọ̀tàlénígba le mẹfa naira niwaju ile igbimọ aṣofin ipiinlẹ naa.

Nigba to n sọrọ niwaju ile naa, Makinde sọ pe eto iṣuna ọhun ko ni ja ireti awọn eeyan ipinlẹ Oyo kulẹ.

Gomina naa tun ṣalaye pe ijọba oun ti ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri ninu ọdun 2020, ati pe igbagbọ oun ni pe aṣeyọri ọdun 2021 yoo dara ju ti 2020 lọ.

Makinde sọ pe bo tilẹ jẹ pe ijọba oun lero pe awọn yoo ṣe iṣẹ bii ida aadọrin ninu aba eto iṣuna ọdun 2020, wọn gbiyanju lati ṣe ida mẹtalelaadọta ninu rẹ.

O fi kun pe idi ti wọn ko fi le ṣe to ohun ti wọn dabaa ninu eto iṣuna ọhun ko ṣẹyin ajakalẹ arun Covid-19 to kọlu gbogbo agbaye.

Biliọnu mẹrindilọgọta le diẹ ni Makinde ya sọtọ fun fun eto ẹkọ, eyii to jẹ ida mọkanlelogun kokari eto iṣuna ọhun.

Makinde ni biliọnu mejila ni eto iṣuna naa fi pọ ju ti eyii to kọja.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ile igbimọ ipinlẹ Oyo, o si fi da wọn loju pe oun yoo maa fi ọwọ sowọpọ pẹlu wọn fun itẹsiwaju ipinlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́