Ilú òyìnbò ní mo lọ lásìkò Covid ló gún mi ni kẹ̀ṣẹ́ láti bẹ̀rẹ̀
Oluwawemimo Tade, obìnrin àgbẹ̀ tó làmìlaaka jùlọ ní ìpínlẹ̀ Ondo ni kò si àwáwí fún ẹnikẹ́ni láti má ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, nítorí lẹ́yìn tí òun fi iṣẹ́ ìjọba sílẹ̀ ní oùn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ oko.
Ìya àfin Tade ní iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní oun kọ́kọ́ jíṣe ní kùtùkùtù ayé òun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àgbẹ̀ ni ìyá àti bàbá òun láti ọjọ́ tí òun ti dáyé.
Tade ni láti ìgbà tí òun ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe isẹ́ okò, sùgbọ́n àyípadà dé ní lọ́dún 2020 lásìkò tí òun lọ bá ọmọ òun tọ́jú ọmọ ní ilú oyìnbó.
"Ilú òyinbo yìí ni Coronavirus de ba mi tí mí o le wálé, sùgbọ́n nítorí ìfẹ́ tí mó ni si iṣẹ́ agbẹ̀ ni mó ba ni mo ba lo ra àwọn nkan ọ̀gbìn, mó gbìn sí ẹyinkule wọn."
Láti asiko yìí ni fọ́ran àwọn èso mi pàápàá jùlọ ti iṣu ṣe tànká gbogbo àgbáyé.
Ó rọ gbogbo ènìyàn pé kí wan máa ṣe ṣe àwáwi lórí ìdá tí wọn kò fi le dáko, nítorí ànfàní tó wà níbẹ̀ pọ̀.