CPC: Irẹsì oloro ti wọ́pọ̀ ní àwọn ṣọ́ọ́bù Akwa Ibom

Ìrẹ̀sì to wọ́n sá sí òòrùn

Oríṣun àwòrán, CPC

Àkọlé àwòrán, Irukera n wo irẹ̀sì ti wọ́n sá s'òòrùn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ikọ ajọ to n ri si ẹtọ àwọn onibàára ni orilẹede Naijiria (CPC) pẹlu iranlọwọ ajọ aṣọbode, ati awọn ọlọpàá ti ya bo awọn ṣọ́ọ́bù kan ni Uyo, olu ilu Ipinlẹ Akwa Ibom, ni bi ti wọn ti ja awọn irẹsi oloro kan gba.

Olori ajọ CPC, Babatunde Irukera ni o sáájú ikọ to lọ Uyo, ni bi ti wọn ti ri bi wọn ṣe n ta àwọn irẹsi naa.

Irukeruka ni awọn ri irẹsi oriṣiriṣi ti o n rùn, ti wọn tun fọ̀ lẹ́yin eyi ti wọn wa sa wọn sinu òòrun nibi ti eku ti n yagbẹ sori rẹ. O ni lẹyin ti wọn ba sa irẹsi naa tan ni wọn yoo wa ko pada sinu apo, ti wọn yoo si wa taa fun awọn ara ilu.

Ìrẹ̀sì to wọ́n sá sí òòrùn

Oríṣun àwòrán, CPCNig/Twitter

Àkọlé àwòrán, Ọ̀ga CPC Babatunde Irukera ni o sáájú ikọ to lọ Uyo

Irukera ni bo ti lẹ jẹ pe awọn irẹsi naa ko dara, ti wọn ba ti fọ̀ọ́ tan, ṣe ni awọn onibara yoo ro pe irẹsi daradara ni.

O tun sọ pe nigba ti awọn wo awọn iresi ti wọn ti di sinu apo lati ta, ṣe ni wọn ri pe irẹsi alawọ̀ oriṣiriṣi lo wa ninu wọn, eyi to fi han pe, oniruuru irẹsi ni wọn n da pọ soju kan.

Olori ajọ CPC naa ni oun ti oju wọn ri ni awọn ṣọ́ọ́bù Uyo ba'ni l'ẹru jọjọ.

Ìrẹ̀sì to wọ́n sá sí òòrùn

Oríṣun àwòrán, CPCNig/Twitter

Àkọlé àwòrán, Irukera n wo irẹ̀sì ti wọ́n sá s'òòrùn

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ ó ranti pe ni ọjọ́ Ajé tó kọjá ni Mínísítà fún Ètò Ọ̀gbin, Audu Ogbeh ké gbàjarè pé orílẹ̀èdè kan ń pèsè ìrẹsì olóró.

Ijọba Apapọ sọ ni igba naa pe awọn yoo ti ibode orilẹede Naijiria pẹlu orilẹede naa lati dẹkun kiko irẹsi oloro naa wọle lati ibẹ.

Ṣugbọn bawo ni irẹsi buruku wọnyii ṣe wọ Naijiria ti o si di tita lori igba?

Olori ajọ CPC ni, o dabi ẹni pe awọn kan ko ṣiṣẹ wọn to ni o.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post