APC Convention: Níbo ni kárá ìlú gbà ní Abuja lónìí?

Pẹ̀lú òjò wẹliwẹlí tó gbòdee ní ìlú Abuja, àwọn ènìyàn ti ń lọ síbi ìpàdé ìpádé àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọ́ṣèlú APC tó ń wáyé ní Eagle Square.
Ní ibi ìpàdé ọ̀hún ní wọ́n ó ti máa yan àwọn ti yóò sojú ẹgbẹ́ fún ọdún mẹrin mííràn láti darí.

Oríṣun àwòrán, Gloria adagbon/twitter
Ní báyìí ìgbìmọ̀ elétò fún ìpàdé náà ti fi atẹjade síta f'àwọn ènìyàn tó ń wọ ìlú Abuja.
Àtẹjade naa juwe pé gbogbo ọkọ̀ tó bá ń bọ̀ láti òpópónà Sheu Shagari yóo gba ọ̀nà Ralph Sodeinde lẹ́ba Bullet Building to fi já sí Central Business District.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Wọ́n tún ni àwọn máa dári ọkọ̀ láti òpópónà Kur Mohammed tàbí Constitution Avenue lẹ́gbẹ̀ Benue Building láti já sí Central Business District.
Kayode Opeifa to jẹ akọ̀wé Ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ìgòkègbodo ọkọ̀ nílù Abuja sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rísí ìdári ọkọ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò míràn ti wa lẹnu iṣẹ láti mójú tó àwọn súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀.









