APC: Convention: Ọ̀wàrà òjò balẹ̀ ní gbàgede Eagles Square

Gbagede Eagles square
Àkọlé àwòrán, Ọwara ojo to bẹ silẹ nilu Abuja sé ọpọ awọn olugbe ilu naa mọle

Ọwara ojo to bọ lulẹ lowurọ ọjọ Abamẹta lo ni kò tíì jẹ́ ki ìpade idibo apapọ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Abuja bẹ̀rẹ̀.

Ipade idibo apapọ ẹgbẹ oṣelu naa ti wọn fi si agogo mẹwa owurọ ni ko tii bẹrẹ titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Ọwara ojo to bẹ silẹ nilu Abuja se ọpọ awọn olugbe ilu naa mọle.

Gbagede Eagles square nilu Abuja
Àkọlé àwòrán, Awọn aṣoju lati gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji orilẹ-ede Naijiria ati olu ilu rẹ nilu Abuja ni yoo kopa nibi ipade apapọ naa

Amọṣa, ẹgbẹrun meje o din igba aṣoju ni yoo kopa ninu ipade apapọ naa nibi ti wọn yoo ti dibo yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa fun sdun mẹrin miran.

Lara awọn eekan to ti gunlẹ si gbagede Eagles square nibi ti ipade naa yoo ti waye ni gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Gomina, minisita fọrọ abẹle, Abdulrahman Dambazau pẹlu Gomina ana nipinlẹ Sokoto, Aliyu Wamako.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn aṣoju lati gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji orilẹede Naijiria ati olu ilu rẹ nilu Abuja ni yoo kopa nibi ipade apapọ naa.

Àkọlé fídíò, SARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro
Àkọlé fídíò, Ìyìn, ati ìmọ̀ràn fún Super Eagles