Ìdìbò Ekiti: Tinubu, Oyegun síde ìpolongo ìbò Fayẹmi

Oríṣun àwòrán, @akandeoj
Igbákejì ààrẹ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tí gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ekìtì láti sojú ààrẹ Muhammadu Buhari fún ìsíde ìpolongo ìbò fún olùdíje tó ń dúpò Gómìnà, lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ( APC), Ọ̀mọ̀wé Kayode Fayemi ní ìpínlẹ̀ Ekìtì.
Ní ibi àyẹyẹ ọ̀hún, ọ̀jọ̀gbọ́n Osinbajo rọ gbogbo àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ekìtì láti lé ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) kúrò ní ìjọba.
Ó ní àsìkò ti tó, láti dá Òmòwé John Kayode Fayemi pada sórí àléfà láti jẹ̀gbádùn ètò ìjọba àwá-ara-wa.
Ìgbákejì ààrẹ ní àsìkò ìnirá ti dópin nípínlẹ̀ Ekiti, tí Fayemi bá gbà ìjọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òsèlú APC, aìmọye àwọn àgbàgbà ẹgbẹ́, àti àwọn Minisita ló kọ́wọ̀ọ́rìn pèlú igbákejì ààrẹ.
Lara wọn la ti ri asaaju ẹgbẹ APC< Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati alaga ẹgbẹ oselu APC lorilẹ-ede yii, John Odigie Oyegun.
Ẹ̀wẹ̀, kí igbákejì ààrẹ tó kúrò ní Abùjá, lo tí gbàlejò àwọn asojú ilé iṣẹ́ láti orílẹ̀èdè Germany, fún ìjíròrò lórí ètò ọrọ̀ ajé àti okoòwò.








