Tenancy: Njẹ́ o mọ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ayálégbé?

Àkọlé fídíò, Tenancy: Njẹ́ o mọ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ayálégbé?

Ọpọlọpọ igba ni lanlọọdu ati ayalegbe maa n ni wahala pẹlu ara wọn lorilẹ-ede Naijiria.

Awọn miran tilẹ maa n gbe ara wọn lọ si agọ ọlọpaa tabi ile ẹjọ.

Sugbọn ṣe iwọ gẹgẹ bi ayalegbe mọ ẹtọ rẹ tabi ni òye awọn nkan to ṣe pataki fun ọ lati mọ ki o to gba ile gbigbe.

Amofin Ayọrinde Ajiṣafẹ ba BBC News Yoruba sọrọ lori awọn ohun to yẹ ko o mọ ko to o gba ile àti igbesẹ to yẹ koo gbe gẹgẹ bii onile.

Amofin naa fi kun ọrọ rẹ pe, o ni lati faramọ ofin ti onile ba ka silẹ. "Ti o ba mọ pe ko tẹ ọ lọrun, ko pọn dandan koo gba ile naa.

Too ba ti gba a, a jẹ pe o faramọ niyẹn."

Bakan naa lo sọ pe ayalegbe le fi owo rẹ tun ile ṣe to ba fẹ ẹ gba ile, pẹlu ijiroro pẹlu lanlọọdu rẹ.

"Sugbọn, o gbọdọ rii daju pe, ẹ kọ ọ sinu iwe kan, ti ẹ si jọ buwọlu. Ti ko ba si ni akọsilẹ, o le sọ pe oun ko sọ bẹ lọjọ iwaju.

Ni afikun, amofin to n ba awọn eniyan moju to ile wọn naa sọrọ lori awọn ofin to daabobo onile ati ayalegbe laisi wahala ni Naijiria.

Lanlọọdu rẹ ni ẹtọ lati maa fun ọ ni owo ti o gba lọwọ rẹ silẹ pe owo to o bá ba nkan jẹ, ti o ba fẹ ẹ fi ile naa silẹ. "

O sọ pe awọn lanlọọdu maa n ṣe eyi lati daabo bo ara wọn lọwọ awọn ayalegbe to ba jẹ basejẹ. Igba mi i gan wa to jẹ pe owo ti wọn san silẹ ko ni ka nkan ti ayalegbe bajẹ ninu ile.

Bakan naa ni lanlọọdu rẹ le gbe ọ lọ sile ẹjọ ti o ba kọ lati san owo ile rẹ.

Nigba ti a bere lọwọ amofin boya ofin orilẹ-ede Naijiria ni awọn lanlọọdu n tẹle, Amofin Ajiṣafẹ ṣalaye pe ''ofin orilẹ-ede Naijiria ko sọ nkan ti lanlọọdu le ṣe ninu ile rẹ. Lanlọọdu kọọkan lẹtọ lati ṣe ofin to ba wu u. Iwọ ni ko mọ boya o tẹ ọ lọrun tabi ko tẹ ọ lọrun ki o to o gba a."

Ẹwẹ, o sọ pe lanlọọdu le sọ fun ọ pe oun yoo da owo rẹ pada fun ọ, ti o ba fẹ ẹ ko jade ninu ile, ti o ko si ti i lo owo ti o san tan. Amọ o le sọ fun ọ pe oun ko ni le da a pada digba ti oun ba ri ẹlomii gba sinu ile.

"Ayalegbe lo gbọdọ tun nkan to ba bajẹ ninu ile to n gbe ṣe, ayafi to ba jẹ ita nibi ti gbogbo awọn to yale gbe nlo. Wọn gbọdọ jẹ ki lanlọọdu wọn mọ si."