Eko: A ti din lara owo-ori ilẹ ati ile ku

Awọoran Ambode lasiko to n tọwọ bọ iwe

Oríṣun àwòrán, @AkinwumiAmbode

Àkọlé àwòrán, Gomina se ileri lati se awọn akanse isẹ tuntun mii

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ wipe awọn ti din owo ori ilẹ ati ọkọ ku ni ipinlẹ Eko, gẹgẹbi ipinnu wọn lati bẹrẹ si ni gba owo ori naa laipẹ.

Owo ori ilẹ ati ọkọ ti wọn sọ wipe gbogbo awọn to ni ile yoo ma san lati mu igbayegbadun ba awọn ara ilu ati fun ipese ohun amayedẹrun.

Sugbọn, awọn eniyan ko faramọ ipinnu ijọba ipinlẹ naa, eleyi to mu ki ijọba naa din iye owo ori to yẹ ki wọn san ku.

Nibayii, ijọba ipinlẹ Eko yoo din ida ọgọrun kuro lara owo ori ilẹ to yẹ ki awọn to nfi ilẹ wọn se okoowo san, eleyi to tunmọ si wipe, ẹni to yẹ ko san ẹgbẹrun mọkanlelaadọrun ati igba naira (N91,200) tẹlẹ, yoo wa san ẹgbẹrun marundinlaadọta ati ẹgbẹta naira (N45,600) lọdun bayi.

Awọn ile ti laarinlọọdu ba n gbe, ti wọn tun fi n pese awọn ohun eelo lawujọ, ni wọn ti din ida marundinlọgbọn kuro lara owo ori ilẹ wọn, dipo ki wọn san ẹgbẹrun lọna ọgbọn ati okoolelẹẹdẹrin naira (N30,720) tẹlẹ, wọn yoo maa san ẹgbẹrun lọna mẹtalelogun ati ogoji naira (N23,040) bayi lọdọọdun.

Awọn eeyan nrin laarin ẹkun omi to ti gba opopona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Owo ori lona abayọ si isoro l' Eko

Bakan naa, ijọba ipinlẹ Eko ti din iye owo to to ida marundinlogun kuro lara iye owo ori ilẹ to yẹ ki awọn onile tẹlẹ, eleyii yoo mu ki wọn O san N7,752 lọdọọdun.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Ijọba ipinlẹ Eko, labẹ Gomina Akinwunmi Ambode wa parọwa si awọn tọrọ naa kan lati kọpa ninu agbekalẹ aba kan nile asofin ipinle naa, lati le mu ki awọn eniyan fi ero wọn han lori abadofin owo ori ilẹ ati ile ni ipinle Eko.