Eko: Ambọde nfẹ ki wọn fi Yoruba kọrin orilẹede wa

Awọoran Ambode lasiko to n tọwọ bọ iwe

Oríṣun àwòrán, @AkinwumiAmbode

Àkọlé àwòrán, Gomina se ileri lati se awọn akanse isẹ tuntun mii

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode ti pasẹ fawọn akẹkọ nileewe ijọba ati taladani lati maa kọrin orilẹede Naijiria ni ede Yoruba, lọna ati gbe ede Yoruba larugẹ ati lati paamọ fun ọjọ iwaju.

Bẹẹ ba si gbagbe, Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode losu to kọja tun buwọlu ofin to fagbara fun ede Yoruba nipinlẹ naa.

Igbakeji gomina nipinlẹ Eko, Ọmọwe Idiat Adebule lo fi asẹ gomina naa jisẹ nibi ipade to se pẹlu awọn adari ileẹkọ tijọba nipinlẹ Eko.

Arabinrin Adebule naa salaye pe ede Yoruba naa ni wọn yoo sọ di ẹkọ to pọn dandan fawọn akẹẹkọ ninu awọn imọ ẹkọ ti wọn yoo maa kọ wọn.

Gomina Ambọde lọjọ kẹjọ, osu Keji, ọdun yii, tun buwọlu abadofin to fagbara fun ede Yoruba gẹgẹbi ede ibaraẹnisọrọ nibudo itaja ati idokowo nipinlẹ Eko.