Ambọde: ọọdunrun owo ori lo wa f'awọn eeyan Eko lati san

Akinwunmi Ambode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amde ni ko si bi n se lee se naa ti ko ni gba owo

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambọde ti sọ wi pe ọọdunrun ni iye awọn nkan to yẹ ki awọn olugbe ipinlẹ Eko maa san owo ori le lori.

Gomina Ambọde ni owo ori lori ilẹ ati ile ti ijọba oun ni ki araalu san jẹ ọkan lara wọn ati wi pe bi oju ọjọ ṣe ri ni ko jẹ ki wọn da'wọ le awọn yooku.

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi sọ eleyi di mimọ lasiko to fi n ba awọn eeyan sọrọ lori ofin dandan lowo ori ilẹ ati ile eleyi ti ipinlẹ Eko kede pe ohun yoo bẹrẹ si ni gba laipẹ yii.

Awọn eeyan nri laarin agbara omi to ti gba opopona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Owo i ni ipese amayerun l' Eko

"Mo fẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Eko mọ wi pe, o le ni ọọdunrun awọn owo ori to yẹ ni sisan.

"Ṣugbọn ti a ko tii fi ọwọ kan yatọ si owo ori lori ilẹ ati ile yii ati boya ẹyọkan miran.

"Mo fẹ kẹẹ mọ wi pe ijọba to mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ ni wa. Ohun ti araalu ba fẹ ni ijọba a ba wọn fẹ", Ambọde wi.

Gomina sọ pe gbogbo awọn ohun elo amayedẹrun ti o nfarahan ni ilu Eko ti awọn eeyan n kọ haa si naa lo ni owo to ba de.

"Kii ṣe nitori oni bi kose nitori ọjọ iwaju. Bi idagbasoke yoo ba de ba ipinlẹ Eko, a ni lati se awọn ohun kan.

"Sugbọn pẹlu ijiroro ti a ti ni pẹlu awọn araalu lori ofin dandan lowo ori ati ilẹ yii, o di dandana ki a wa nkan se sii."

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: