Aarẹ Buhari lọ si'pinlẹ Yobe fun abẹwo ọlọjọ kan

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe abẹwo si ipinlẹ Yobe loni ọjọọru.
Agbẹnusọ fun aarẹ to kede ọrọ naa wipe Aarẹ Buhari ṣe'pade apero pẹlu awọn alẹnulọrọ n'ipinlẹ Yobe lori eto aabo to mẹhẹ nibẹ eleyi to ṣ'okunfa bi ikọ Boko Haram ṣe ji awọn ọmọbinrin akẹkọ gbe nipinlẹ naa laipe.
Basir Ahmad sọ loju opo ayelujara twitter rẹ pe Aarẹ ti ṣe ipade pẹlu awọn obi ọmọbinrin akẹkọ to wa ni'gbekun Boko Haram nilu Damaturu.
O ṣalaye siwaju sii pe Aarẹ ti pinu lati ṣe abẹwo s'ipinlẹ Zamfara ati Rivers pẹlu.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Yobe, Abdullahi Bego sọ fun ileeṣẹ BBC wipe ijọba ipinlẹ naa ti ṣetan lati gbalejo aarẹ ati wipe awọn ni ireti wipe aluyọ yoo ba eto aabo ati awọn ohun miran ti wọn nreti lati ọdọ ijoba apapọ.
Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu keji, ọdun 2018 ni ikọ Boko Haram kọlu ileẹkọ girama fun awọn obinrin nilu Dapchi nipinlẹ Yobe ti wọn si ko aadọfa akẹkọ lọ nibẹ.
Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:








