Kíni èròngbà ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lórí àwọn tó ń ta ọtí lágbègbè ilé ẹ̀kọ́? Àlàyé réè

Aworan olukọ nile ẹkọ ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, lasgeducation

Bi o ba pada wa daṣẹ, wọn ko ni le da ile ọti sẹgbẹ awọn ileẹkọ nipinlẹ Eko bo ba ya.

Idi ni pe ijọba ipinlẹ naa n gbero lati kọdi idasilẹ awọn ile ọti ati aaye faaji mii silẹ layika tabi ni itosi awọn ile ẹkọ ni ipinlẹ ọhun.

Bẹẹ naa la gbọ pe ipinlẹ naa n fikun lukun pẹlu awọn alẹnulọrọ lori sisun iye ọjọ ori ifẹyintilẹnuṣẹ si ọdun marundinlaadọrin dipo ọgọta ọdun fawọn olukọ to n ba ijọba ṣiṣẹ.

Kọmiṣana feto ẹkọ alakọbẹrẹ ati ti ile ẹkọ girama Ọgbẹni Jamiu Alli-Balogun lo mẹnu ba ọrọ yi lasiko to n dahun ibeere lọwọ awọn akọroyin nibi ipade igbimọ to n mojuto eto ẹkọ labẹ ijọba apapọ Naijiria.

O ṣalaye pe aba lati fofin de idasilẹ ile ọti lẹgbẹ ile ẹkọ jẹ ọkan lara ọna ti ijọba fẹ fi koju tabi mu adinku ba iṣẹlẹ lilo oogun oloro ati awọn iwa aburu mi paapa laarin awọn ọmọde ati ọdọ nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ''iwadii fihan pe awọn eeyan a maa ta oogun oloro lawọn ile ọti atiaaye faaji mii ti eleyi ko si le so eso rere fawujọ.''

O ni ''a ti ṣe agbekalẹ awọn ẹgbẹ alamojuto kan lawọn ile ẹkọ wa taa si ni ajọṣepọ pẹlu awọn agbofinro bi ọlọpaa,ileeṣẹ aṣọbode awọn lọbalba ati awọn mii''

O tẹsiwaju pe awọn ti ṣe agbekalẹ ipolongo ni ilu Epe gẹgẹ bi apẹrẹ ibaṣepọ pẹlu awọn agbofinro lati polongo aburu to wa ninu lilo oogun oloro ati awọn iwa ibajẹ mii.

''A o danu duro.Ajọṣepọ laa n ṣe.A n sọrọ soke lati fi tako awọn iwa ibajẹ to n waye lawujọ.''

''Tori naa la fi n wa gbogbo ọna lati mu iyipada wa ki a si tẹsiwaju pẹlu ero wa lati tako idasilẹ ile ọti lagbegbe awọn ile ẹkọ wa.''

O ni bi awọn akẹkọọ ba n ri awọn eeyan layika wọn ti wọn n mu ọti tabi hu iwa aburu mii, eleyi le mu kawọn fẹ bawọn kopa ninu iwa bayii.

O ṣalaye pe aba ṣi ni awọn n da ti ijiroro lori rẹ yoo si pada waye niwaju ile aṣofin.

Lẹyin igba naa to ba di ofin lo ni awọn to le ṣe amulo rẹ.

Amọ o sọ pe awọn ko mọ igba ti eleyi yoo di itẹwọgba lọdọ ijọba.