Ebi pa èèyàn tó lé ní 170 kú ní nítorí ọ̀gbẹlẹ̀

Ethiopia drought

Oríṣun àwòrán, getty images

O kere tan, eeyan 176 lo ti ku lagbegbe Tigray, lorilẹ-ede Ethiopa lẹyin ebi to n pa awọn eeyan naa latari ọgbẹlẹ to n waye nibẹ.

Alakoso ẹkun Tigray, Hadush Asemelash, sọ fun ileeṣẹ iroyin Tigray TV pe ọkunrin mọkanlelọgọrun ati obinrin márùndínlọ́gọ́rin lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Gomina ẹkun Emba Sieneti, Kidanmariam Surafel sọ pe lọwọ yii, nnkan bii ẹgbẹrun marundinlaadọta eeyan ni ebi n pa.

Ebi naa ki ba ma ti buru to bo ṣe wa lakoko yii bi ko ṣe ti ogun abẹle ọlọdun meji to waye ṣaaju.

Ijọba ilẹ naa sọ pe iye eeyan to n fi ile wọn silẹ latari ọgbẹlẹ naa ati airi ohun elo iranwọ gba ti pọ ju ti tẹlẹ lọ.

Lọsẹ to kọja ni ijọba fidihẹ Tigray kede ilu o fararọ lẹyin ti eeyan to le ni igba jade laye nitori airi ounjẹ jẹ, eyii to waye nitori ọgbẹlẹ ọhun.

Igba marun un ọtọtọ to yẹ ki ojo rọ ni ojo kọ lati rọ ni Tigray lati ọdun 2019 gẹgẹ bii ohun ti ajọ UN sọ.

Ṣaaju ni Amẹrika ati UN ti kọkọ fopin si ohun elo iranwọ ti wọn n fi ṣọwọ silẹ naa lẹyin ti wọn ni iwọnba eeyan kereje kan lo n ko wọn pamọ fun lilo ara wọn, eyii to mu ki iṣẹlẹ naa buru siwaju si.

Ọdun kan sẹyin ni ogun abẹle ọlọdun meji to waye ni Tigray pari amọ ija abẹle mii tun ti ṣeyọ lẹkun Amhara, ti ko jina si Tigray ọhun.