Wo bí àwọn abiamọ ṣe ń lòògùn oorun fáwọn ọmọ wọn tí ebi ń pa kí wọ́n lè sùn

Aworan ile iwosan

Oríṣun àwòrán, BBC/AAMIR PEERZADA

Wo ohun ti BBC ba bọ ni Afghanista..

Sohaila Niyazi ọmọ orilẹ ede Afghanistan ṣalaye pe igba ti oun ri owo ra miliki fun ọmọ oun kẹyin ni oṣu meji sẹyin.

Niyazi ni "mo maa n saba rọ"tea" sinu igo lati fun ọmọ mi mu ni."

Niyazi ṣalaye nibi ti o jokoo sí nilẹ ile alamọ to n gbe lori oke ni ẹkun ila oorun ilu Kabul.

Ko sí ọna ti eeyan le gba de ile rẹ - ori ẹrẹfọ to n yọ nikan ni eeyan le gba de ibẹ.

Opo ni Sohaila, o si ni ọmọ mẹfa.

Husna Fakeeri, ọdun kan ati oṣu mẹta ni abikẹhin rẹ.

"Tea" ti Sohaila n sọ nipa rẹ jẹ ounjẹ ti wọn maa n jẹ ni orilẹede Afghanistan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ewe ati omi gbigbona ni wọn maa fi n ṣe e laisi miliki tabi ṣuga.

Sohaila wa lara eeyan miliọnu mẹwàá ti ko ri iranwọ ounjẹ gba mọ lati ọdọ ajọ agbaye UN, nitori airowo ṣe eto naa mọ dáadáa.

Sohaila ni oun ko le jade lọ ṣiṣẹ labẹ ofin ijọba Taliban lati pese ounjẹ fun ẹbi rẹ.

"Igba mii wa lalẹ ti a ko ni ounje ti a le jẹ.

Wọn a fi ebi sun, bakan naa ni ominu yoo bẹrẹ si ni kọ mi ti ilẹ ba mọ.

Awọn ọmọ mi yóò bẹrẹ sí jà si ounjẹ ti ẹbi wa kan ba ti gbe ounjẹ wa fun wa.

Mo maa n pin ounjẹ naa fún wọn ní."

Niṣe ni Sohaila maa n fun omodebinrin rẹ ni ogun oorun ti ebi ba ti n pa a.

"Ọmọ mi máa n sun lati aarọ kan si omiran ti mo bá ti fun un ni ogun oorun.

Mo maa yẹ ẹ o nigba mii lati mọ bo ya o si wa laaye abi o ti ku."

Nigba ti a beere lọwọ rẹ iru ogun ti o fu ọmọ rẹ lo, a rii pe ogun "antihistamine" to maa n jẹ ki eeyan sun ni o n lọ fun ọmọ naa.

Kini Dokita sọ?

Awọn dokita ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ogun naa ko fi gbogbo ara lewu fún agọ ara, o le ṣakoba fun mimi eeyan.

Sohaila ni lọdun 2022 ni ọkọ oun ku ninu ija to bẹ silẹ laarin awọn ọmogun Taliban at'awọn to n gbógun ti wọn ní ẹkun Panjshir.

Lẹyin iku ọkọ rẹ, iranwọ ounjẹ lati ọwọ ajọ UN nipasẹ WFP ni Sohaila fi n ri ounjẹ jẹ.

Ṣugbọn ni bayii, WFP le pese iranwọ ounjẹ fun eeyan miliọnu mẹta pere eyi to din ni ida kan ninu ida mẹrin awọn ti ebi n pa.

Awọn ẹbi at'awọn araadugbo rẹ nikan ni Sohaila gbẹkẹ le bayii lati jẹun.

Aworan iya ati omo

Oríṣun àwòrán, BBC/AAMIR PEERZADA

Awọn mii wo lo tun sọrọ?

Ko dun un wo, o jẹ ọkan lara ọkan lara miliọnu mẹta ọmọde ti ebi n pa gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ Unicef.

Eleyii lo ti buru julọ ninu itan orile-ede Afghanistan gẹgẹ bi ajọ UN ṣe sọ.

Bi ebi ti n pa awọn ọmọde ni Afghanistan, idaduro tun ti ba iranwọ to n gbaruku ti ẹka eto ilera.

Igbimọ ajọ alaanu ICRC lo n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ eleto ilera at'awọn ogun lilo to fi mọ ounjẹ fun ile iwosan bi ọgbọn.

Amọ, ni bayii, ko sí owo mọ lati tẹsiwaju.

Wọn ti da iranwọ owo duro fun ọpọ ẹka eto ilera to fi mọ awọn ile iwosan ọmọde ni Afghanistan, Indira Gandhi ni ilu Kabul.

"Ijọba lo n sanwo oṣu awọn dokita at'awọn nọọsi bayii.

Koda wọn ti din ilaji ku ninu owo oṣu wọn,'' Dokita Mohammad Iqbal Sadiq, adari ile iwosan lo sọ bẹẹ.

Ile iwosan ko le ṣiṣẹ nita mọ, awọn to ba wa nile iwosan nikan ni wọn n tọju.

Wọọdu ọmọde ti ebi n pa kun fọfọ debi pe ọmọ to ju eyokan kan lọ le wa lori bẹẹdi kan.

Sumaya ọmọ ọdun kan ati oṣu meji wa lẹgbẹ kan ninu wọọdu naa.

Mohammad Shafi ọmọ ọdun kan abọ naa wa nínú wọọdu kan naa ti ko dun un wo.

Baba rẹ to ja fun Taliban ku ninu ijamba ọkọ nígbàtí aisan pa iya rẹ.

Mama mama rẹ, Hayat Bibi fi ibanujẹ sọrọ nipa ti bawa sọrọ.

Aworan iya ati omo

Oríṣun àwòrán, BBC/AMIR PEERZADA

O ṣalaye pe ijọba Taliban lo gbe ọmọ ọmọ oun wa sile iwosan amọ oun ko mọ bi ọmọ naa ṣe fẹ ye.

Bibi ni pẹlu oju rẹ to wu sọ pe "mo n tiraka, ori n fọ mi, o dabi ẹni pe ori mi fẹ fọ danu."

Kini Taliban sọ lori ọrọ yii?

A beere lọwọ agbẹnusọ ijọba Taliban, Zabihullah Mujahid ipa wọn lati ri iranwọ gba lọwọ ajọ agbaye.

O sọ pe "wọn dawọ iranwọ duro tori ọrọ aje awọn orilẹ-ede to n ṣe iranwọ ti dẹnu kọlẹ.

Ajakalẹ arun covid-19 ati ogun Ukraine ṣe akoba to pọ.

A ni lati ran ara wa lọwọ bayii, ti ọrọ aje wa ti n ṣe daadaa bayii.

A ti n gbe iṣẹ kọngila iwakusa jade lẹgbẹẹgbẹrun.

Amọ, mi o sọ pe ki wọn da iranwọ duro tori a sí ni ọpọlọpọ ipenija."

O ni ètò ijọba Taliban naa bii igbesẹ ijọba to fofin de awọn wa lara ohun ti ko jẹ k'awọn orilẹ ede kan da iranwọ wọn duro.

Ọrọ to sọ yii ko le dun mọ ọpọ ọmọ orilẹ ede Afghanistan ninu eyi ti ida meji ninu ida mẹta wọn ko ti ri ounjẹ jẹ.

A ba obinrin kan pade niluu Kabul to sọ pe ijọba Taliban ti f'òfin de oun lati maa ta eso, ibọsẹ at'awọn nkan mii loju popo.

O ni wọn ti ti oun mọle ni igba kan ri.

Wọn pa ọkọ rẹ lasiko ogun, o sí ni ọmọ mẹrin lati tọju.

Niṣe ni o bu sẹkun bi o ti n sọrọ.

Obìnrin naa ni "o yẹ kí wọn gba wa l'aye lati maa ṣiṣẹ ki a le máa ri ounjẹ jẹ.

Mo le bura pe a o máa jade lati lọ ṣe isekuse.

Ounjẹ ti awa àtàwọn ọmọ wa yóò jẹ ni a maa n wa lọ.

Aworan awon ati awon iya won

Oríṣun àwòrán, BBC/AMIR PEERZADA

Iranwọ wo ni Taliban ti pese?

O ti n fi dandan ran ọmọ rẹ ọdun mejila jade lati lọ ṣiṣẹ.

"Mo bi ọkan lara awọn Taliban leere pe ounjẹ wo ni mo fẹ fawọn ọmọ mi jẹ ti n ko ba ṣiṣẹ, o sọ pe ki n fun wọn ní majele jẹ ninu ile.

Igba meji pere ni ijọba Taliban fun mi ni owo diẹ," obinrin naa ṣalaye.

Ki awọn Taliban to gba ijọba, idamẹta ninu mẹrin owo ti ijọba n na lo n wa lati awọn orilẹ-ede ilẹ okeere.

Amọ, wọn ti da eyi duro lọdun 2021.

O ṣoro lati ṣalaye iya to n jẹ awọn eeyan Afghanistan.

Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan lo n jẹ burẹdi to ti gan ati omi lasan.