Òní lónìí ń jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo bí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ yóò ṣe gbérasọ

A ti gbáradì fún ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tì yóò wáyé lọ́la ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Oyo - Àjọ OYSIEC

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC ti ṣe afihan igbaradi rẹ saaju eto idibo si ipo alaga ijọba ibilẹ ti yoo waye jakejado ipinlẹ Ọyọ lọjọ Satide.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ laarin ọsẹ yii lasiko ti wọn n pin awọn ohun elo fun eto idibo kaakiri ipinlẹ Ọyọ, alago ajọ naa, Isiaka Olagunju ṣe alaye wi pe gbogbo eto lo ti to fun idibo naa.
Olagunju ni gbogbo ijọba ibilẹ to n bẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni ajọ naa ti pin ohun elo fun eto idibo de lọwọlọwọ bayii, bẹẹ si ni ajọṣepọ wa laarin ajọ naa ati awọn ẹṣọ aabo n'ipinlẹ Ọyọ, lati riidaju pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ.
O kere tan, awọn ẹṣọ eleto aabo bii ẹgbẹrun mẹẹdogun ni ajọ naa ti gba lati mojuto eto idibo naa, bakan naa si ni ajọ naa ti fi iroyin lede nipa igbanisiṣẹ awọn oṣiṣẹ eleto idibo bii ẹgbẹrun lọna ogoji ti yoo ṣe atọkun eto idibo naa jakejado ipinlẹ Ọyọ.
Bakan naa ni ajọ eleto idibo ati awọn agbofinro ti fi idi rẹ mulẹ wi pe ko ni si lilọbibọ ọkọ tabi awọn eeyan to n dede rin kiri laarin aago mẹfa idaji si mẹta ọsan lọjọ idibo.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede wi pe abọ ọjọ ni awọn oṣiṣẹ ijọba yoo fi ṣiṣẹ ni ọjọ Ẹti, ki wọn le gbaradi fun eto idibo naa. Ninu iwe ikede ti akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Olanike Adeyemo buwọ lu, ijọba tọka rẹ wi pe aago mejila ọsan ni ki awọn oṣiṣẹ ijọba ṣiwọ iṣẹ, ki wọn le ni anfani lati gbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ ti too waye lọjọ Abamẹta.











