Dapchi: Àwọn akẹgbẹ́ Leah Sharibu padà sí ilé ìwé, ṣùgbọ́n Leah kò bá wọn wọlé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oṣu mẹsan lẹyin ti awọn agbebọn Boko haram ji aadọfa akẹkọbinrin gbe ni ile iwe kan ni ilu Dapchi ipinlẹ Yobe, ileewe naa ti pada bẹrẹ iṣẹ ẹkọ kikọ bayii.
Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu keji ọdun 2018, gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ wọn kaakiri orilẹede Naijiria, awọn akẹkọ nileewe girama Government Girls'Science and Technical College, Dapchi pẹlu ji lọ si ileewe wọn pẹlu ireti ati gba imọ kun imọ wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọṣa, ọrọ yii pada lọjọ naa eleyi ti o yi itan igbe aye awọn akẹkọ, awọn olugbe ilu Dapchi ati orilẹede Naijiria lapapọ pada nigba ti awọn igara agbebọn kan ti wọn jẹ ọmọ ikọ Boko haram ya bo ileewe naa ti wọn si ko awọn akẹkọ naa lọ.
Lẹyin igba diẹ wọn da awọn kan pada laaye ninu wọn ni oṣu kẹta ṣugbọn wọn ko tii da Leah Sharibu pada.
Ọga agba ileewe girama naa, Hajiya Adama Abdulkarim ṣalaye fun awọn oniroyin pe ida ọgọrin ninu ọgọrun awọn akẹkọ ati olukọ ileewe naa ni wọn ti pada si ẹnu ẹkọ ati iṣẹ wọn.
O ni awọn ti gbe igbesẹ lati pẹtu si awọn akẹkọ ati olukọ naa ninu pẹlu igbesẹ iranwọ gbogbo lati ọdọ ijọba ibilẹ, ipinlẹ lati rii daju pe ẹru ko ba awọn akẹkọ naa ju bi o ti yẹ lọ.
Amọṣa, bi awọn akẹkọ yii ṣe n pada si ẹnu ẹkọ wọn o daju pe Leah Sharibu ti wọn ji gbe pẹlu awọn akẹgbẹ ṣi wa lahamọ awọn agbebọn naa.
Igba ti yoo darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ ni ko tii han si araye.













