Elections 2019 Updates: Buhari ní àjọ INEC kájúẹ̀ láti ṣètò ìbò tó pegedé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria Muhammadu Buhari ni, oun ko ni ṣegbe lẹyin ọmọ ẹgbẹ APC kankan lati yi abajade esi atundi ibo ti yoo waye lawọn ipinlẹ kan.
Buhari wa gba awọn oloṣelu to ba fẹ kopa ninu atundi ibo lawọn ipinlẹ naa nimọran, lati yara lọ mura si iṣe ọwọ wọn, ti wọn ba fẹ gbegba oroke.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ fi sita lọjọ Aiku ni ọrọ yi ti lu sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- INEC-Àwọn jándùkú àti ọmọ ilé ìṣẹ́ ológun lo dá ètò ìdìbò Gómìnà Rivers rú
- Wike fẹ́ lò wá láti da ìdìbò rú pẹ̀lú rìbá - Iléeṣẹ́ ológun
- APC gba ìjòkò tó pọ̀ jùlọ ní ilé aṣòfin àgbà
- A tún ti ṣàwárí omi àjèjì míràn ní Ilé-Ifẹ̀ - Ọọ̀ni
- Òkùnkùn biribiri ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà nílẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó na òṣìṣẹ́ àjọ amúnáwá
- Bàbá pokùnso ní àhámọ́ lórí ẹ̀ṣùn pé ó bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀
Garba Shehu, to jẹ oluranlọwọ agba fun aarẹ Buhari feto iroyin ni, awọn aarẹ nigba kan ri a ma dasi ibo lati le gbe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn sugbọn Buhari ko ni ṣe bẹẹ.
Ọrọ Buhari yii si lo dabi eyi to tako nnkan ti ẹgbẹ rẹ, APC sọ pe igbesẹ Inec lati ṣeto atundi ibo ni ipinlẹ Rivers lodi si ofin.
Lanre Issa Onilu, to jẹ akọwe ipolongo APC sọ pe, ''wọle wọde laarin Gomina Nyesom Wike ati Inec jẹ ohun ti ko fi awọn lọkan balẹ''

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria
Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, lẹyin idibo Gomina ati ti ile asofin lawọn ipinlẹ kan, kede pe awọn yoo tun ibo di nitori awọn aiṣedede kan to waye lasiko ibo.
Ipinlẹ Adamawa ,Bauchi, Benuẹ, Kano ati Sokoto si wa lara awọn ipinlẹ ti atundi ibo yoo ti waye.
Ninu awọn ibi ti atundi ibo yoo ti waye naa, la ti ri awọn ipinlẹ ti ẹgbẹ APC ti n ṣe ijọba, ti ọrọ naa si kan awọn Gomina ipinlẹ to wa latinu ẹgbẹ alatako PDP naa .
Buhari tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, bi awọn ọmọ ẹgbẹ ti ṣe n bẹnu atẹ lu oun pe, o yẹ ki oun da si ibo naa ni awọn alatako n sọ pe, ko yẹ ki oun da si.
O wa pari ọrọ rẹ pe, ajọ eleto idibo Inec kun oju osuwọn lati ṣeto idibo to yanranti gẹgẹ bi iṣe wọn.













