UFC248: Israel Adesanya ti fi ẹ̀ṣẹ́ yanjú Romero ní ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria ni, Iṣrael Adesanya ṣi ni ẹṣin iwaju ti gbogbo tẹyin n wo sare ni ere idaraya ẹṣẹ ati ipa kikan, iyẹn UFC248 ni ipele middlewight.
Israel Adesanya to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun lorilẹede Naijiria fi agba han Yoel Romero ninu idajọ gbogbo awọn adajọ to mojuto ija naa.
Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ awọn onworan lo fẹhonu han pe ija naa ko dun bi awọn ṣe lero, sibẹ gbogbo awọn onidajs mẹtẹẹta to wa nikalẹ fun ija naa ni wọn gbe idajs kalẹ pe ọwọ Adesanya lo dun Romero julọ lasiko ija naa.
Ninu ọrs to sọ lẹyin ija naa, Adesanya ṣalaye pe ija naa ko rọgbọ, ṣugbọn gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lati bori ni oun ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu ija yii, Adesanya ti ja ija mọkandinlogun, o si ti bori gbogbo rẹ.
Nibayii, ti Romero ti kuro, ọna la fun ija laarin Adesanya to wa loke tente atẹ igbelewọn awọn akanṣẹ ni ipele Middlewieght, ija ẹṣẹ ati ipa kikan UFC248 lati koju Paulo Costa to wa ni ipo keji lori atẹ naa.
Pẹlu abajade ija naa, Romero ti padanu marun ninu ija mejidinlogun to ti ja, mẹtala ninu rẹ lo bori. O si tun yọju sita pe mẹrin ninu ija marun to ja sẹyin ni ṣisẹ-n-tẹle lo ti padanu bayii.
Romero ni, "nṣe lo kan n sare kaakiri oju agbo ija" o fi kun un pe ija ajakuorogbo lawọn eeyan wa wo, ohun si ni wọn sanwo fun lati wo kaakiri agbaye.













