Fury vs Wilder: Ìbínú ni Wilder fi kúrò níbí ìjà, tó sì ní síbẹ̀-síbẹ̀, akọni ni òun

Oríṣun àwòrán, @peluu_lovers
Tyson Fury ti fagba han Deontay Wilder lẹyin to na jati-jati ninu idije ẹṣẹ kikan to waye laarọ ọjọ Aiku, ni gbọgan MGM, to wa ni Las Vegas.
Alubami ni Fury, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Gẹẹsi lu Deontay, to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika ninu idije ife agabaye ọhun.
Fury ni ẹni ti ọwọ rẹ moke ju ninu ija naa, igba keji si ree ti wọn yoo pade lori papa, ṣugbọn ninu abala keje ija ọhun lo ti fọ Wilder lẹnu tan patapata, ti onitọun ko si lee ta putu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Boko Haram tún ṣọṣẹ́ ní Adamawa, ọ̀pọ̀ òkú ṣùn, àìmọye dúkìá jóná
- Ọjọ́ burúkú, èṣù gbomi mu ní Ṣagamu nígbà tí agbábọ́ọ́lù kan dèrò ọ̀run
- Oluwo kò gbọdọ̀ kọrin òwe tàbí bá àkọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, kó má baà ba ẹjọ́ ara rẹ̀ jẹ́ - Ọ̀ràngún ṣàlàyé
- BBC Yorùbá gba àmì ẹ̀yẹ akọni nídìí àgbéga àṣà àti èdè abínibí
- Ẹ má sọ Amotekun di ẹgbẹ́ OPC, ẹ fi wá sínú ẹ̀ṣọ́ aláàbò - Miyetti Allah
- Buhari, kí ló dé tó fẹ́ dá $100m owó Abacha padà fún gómìnà Kebbi? - Amẹ́ríkà fọnmú
Nnkan bi ọdun kan o le diẹ sẹyin ni wọn kọkọ pade, ṣugbọn awọn to n ri si ija naa ni ọmi ni wọn ta lọjọ naa lọhun.
Eyi si mu ki wọn mu ọjọ ija mii, ti awọn afẹṣẹku bi ojo mejeji si ti n leri tantan mọra wọn lọpọ igba ti wọn ba pade.
Lẹyin ija ọhun, ti wọn si kede Fury bi ẹni to moke julọ, lo gba igbanu gẹgẹ bi ẹni to le ja ẹṣẹ ju ninu idije WBC lagbaye, eyi ni WBC World Heavyweight.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dọ́wọ́jọ di ẹrù wíwo lé Mourinho àti Tottenham lórí
- Oluwo kò gbọdọ̀ kọrin òwe tàbí bá àkọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, kó má baà ba ẹjọ́ ara rẹ̀ jẹ́ - Ọ̀ràngún ṣàlàyé
- Ààrẹ Gnassingbe díje fún sáà kẹ́rin, òun àti bàbá rẹ̀ ti ṣèjọba Togo fún àádọ́ta ọdún lé mẹ́ta
- Jospeh Yobo ti di igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tuntun
Ibanujẹ ni Wilder fi kuro ni gbọgan MGM ti ija naa ti waye nigba to sọ pe "Ẹni to lee ja ju lo bori, jagunjagun ni mi, ṣugbọn ko si awawi."
Ni ti Fury ni tirẹ, o sọ fun awọn oniroyin lẹyin ija naa pe "Ọba ti pada bọ sori itẹ," lẹyin naa lo gboriyin fun Wilder pe iṣe lo ṣe.
O ni "Mo fẹ gboriyin fun Deontay Wilder fun iṣe takuntakun to ṣe, o ja fitafita titi di abala keje ija ọhun, ṣugbọn ọba ti pada sori itẹ rẹ."
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ ẹṣẹ jija ti bẹrẹ si ni fi erongba wọn lede lori ija naa, ti wọn si ti n ki Tyson Fury ku ori ire.













