Chelsea vs Tottenham: Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dọ́wọ́jọ wó òrùlé Stamford Bridge lu Mourinho àti Tottenham

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbaọjẹ agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, to ti di akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa bayii, Frank Lampard lo moke ninu ija oun ati ọga rẹ, Jose Mourinho ni papa iṣere Stamford Bridge lọsan ọjọ Satide.
Atamọtaṣe, Olivier Giroud lo gbayo alakọọkọ wọle fun Chelsea nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mẹẹdogun.
Lẹyin iṣẹju mẹta ti wọn bẹrẹ abala keji ere bọọlu ọhun ni adilemu, Marcos Alonso gba ayo keji sawọn Tottenham Chelsea.
- Oluwo kò gbọdọ̀ kọrin òwe tàbí bá àkọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, kó má baà ba ẹjọ́ ara rẹ̀ jẹ́ - Ọ̀ràngún ṣàlàyé
- "Mo le jẹ iná, fi iná ra ara, fi omi tan iná láti pa owó gidi láì ṣe oníṣàngó"
- Toyin Abraham ọkọ rẹ̀ àti Ire ní London, Odunlade 'kòlábò' pẹ̀lú Mercy Aigbe
- Olùkọ́ tó fi tipá gba ìbálé akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ wọ fásitì rí ẹ̀wọ̀n ọdún 21 he
- Bàbà ìyàwó ló yẹ kí ọkùnrin dọ̀bálẹ̀ fún, kìí ṣe ìyàwò tó fẹ́ fẹ́ - Yemi Elebuibon
- Ọ̀ọ̀ni kò láṣẹ láti yọ mí nípò, mi ò sì ní ááwọ̀ mọ́ pẹ́lú Aláàfin-Oluwo
Nisẹ ni akọnimọọgba Tottenha, Jose Mourinho dori kodo lẹyin ti ọwọ iya ba ikọ agbabọọlu rẹ Tottenham Hotspurs.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Mourinho ti ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fun igba meji ọtọọtọ.
Amọ Eric Lamela to wọle da ayo kan pada eyi to jẹ ki ere bọọlu pari si ayọ meji si ẹyọkan.








