Pete Edoche: Elebuibon ní tá bá ṣọ́ra, àṣà àjèjì yóò sọ wá dẹrú òyìnbó

Igbeyawo

Oríṣun àwòrán, @theknot

Araba awo ilu Oshogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti sọ pe, ki ọkunrin maa kunlẹ lati beere lọwọ ọrẹbinrin rẹ pe ko fẹ oun, kii ṣe aṣa ilẹ Yoruba,o ni iwa ajeji naa ni asa ọhun.

Elebuibon lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, lori ọrọ ti ọkan lara awọn agba ọjẹ oṣere tiata lorilẹ-ede yii, Pete Edoche sọ pe, oponu ati ọdẹ ni ọkunrin to ba n kunlẹ fun obinrin lati beere pe, ko gba ki oun lee fi ṣaya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Elebuibon ni awọn oyinbo alawọ funfun lo ma n ṣe iru nnkan bẹẹ, ati pe ko si ninu aṣa ilẹ Yoruba.

O ni awọn oyinbo lo ma n ṣe bẹẹ, kii ṣẹ aṣa tiwa pẹlu afikun pe, ti ọkunrin ba fẹ gbeyawo laye ijọun nilẹ Yoruba, n ṣe lo maa n kọkọ ṣe iwaadi iru ile ti obinrin bẹẹ ti jade wa.

Fayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, others

"Lẹyin naa alarena yoo tọ ẹbi obinrin ọhun lọ, kii ṣe pe ki ọkunrin mu oruka lọwọ, ko si kunlẹ lati beere pe ki obinrin fẹ ọhun."

Elebuibon tẹsiwaju pe, awọn obi obinrin lo yẹ ki ọkunrin dọbalẹ fun lati beere pe ,oun fẹ fi ọmọ wọn ṣaya, kii ṣe obinrin naa.

Ni ti aye to daye ọlaju, Elebuibon ni "Kii ṣe gbogbo nnkan ni a gbọdọ maa tẹle pẹlu ọlaju, a ko le sọ pe aye ti daye ọlaju, ka foju ẹgbo tẹ ilẹ."

Àkọlé fídíò, Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Elebuibọn pari ọrọ pe, iwa ọlaju maa n koba eeyan ni, ti ko si n jẹ ki eeyan ni ami idanimọ gẹgẹ bi ọmọ ilẹ Yoruba atata.