Togo Elections: Ààrẹ Gnassingbe díje fún sáà kẹ́rin, òun àti bàbá rẹ̀ ti ṣèjọba Togo fún àádọ́ta ọdún lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ orilẹede Togo jade lonii ọjọ Abamẹta lati dibo yan aarẹ tuntun ti yoo tukọ ilẹ naa fun saa miiran
Aarẹ Faure Gnassingbe to wa lori aleefa lọwọlọwọ n dije fun saa kẹrin lẹyin to di aarẹ ilẹ Togo lọdun 2005 nigba ti baba rẹ, Eyadema Gnassingbe aarẹ orilẹede naa tẹlẹ papoda.
Eyadema fipa gbajọba lorilẹede Togo lọdun 1967, o si jẹ aarẹ ilẹ naa to fi di ọdun 2005 to ku.
- Èmi sì ní Oluwo tilẹ̀ Iwo, kò sí ìgbìmọ̀ ọba kankan tó lè ní kí ń rọ́ọ́kún nílé - Oluwo
- Toyin Abraham ọkọ rẹ̀ àti Ire ní London, Odunlade 'kòlábò' pẹ̀lú Mercy Aigbe
- Èlé owó iná ọba kọ́ ló kàn, ẹ kọ́ ṣàtúnṣe sí ìlànà àdánú tẹ́ ń ṣe fún wa - Iléeṣẹ́ apínná sọ fún ìjọba
- Àdínkù bá owó ojúmọ́ ọlọ́kadà l‘Ọyọ láti ₦200 si ₦100, owó gbígbà bẹ̀rẹ̀ lónìí
- A fẹ́ ìtọ́jú fún Boko Haram tó bá ronúpìwàdà, ẹ dá iléeṣẹ́ sílẹ̀ fún ìtọ́jú wọn - Ilé aṣòfin
- Toyin Abraham ọkọ rẹ̀ àti Ire ní London, Odunlade 'kòlábò' pẹ̀lú Mercy Aigbe
- Maryam Sanda pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lóri ìdàjọ́ ikú
Ọmọ rẹ, Faure to ti ṣe ijọba fun saa mẹta ọtọọtọ, n gbegba ibo aarẹ fun saa kẹrin lati tẹsiwaju ijọba ẹbi Gnassingbe lorilẹede Togo.
O ti le ni aadọta ọdun bayii ti ẹbi Gnassingbe ti n ṣe ijọba orilẹede Togo.
Lati le dẹkun awọn alatako rẹ, aarẹ Gnassingbe ṣe agbekalẹ ofin kan eyi to sọ pe aarẹ ilẹ Togo ko le lo ju saa meji ọlọdun marun un marun un lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eleyi tumọ si pe Gnassingbe si le jẹ aarẹ orilẹede naa di ọdun 2030 to ba wọle idibo gbogbogbo toni ati to ba tun ṣe saa kan sii.
Gnassingbe ṣeleri pe oun ṣetan lati tun ọrọ aje orilẹede Togo ṣe ti oun ba wọle.
Iṣẹ ati oṣi n ba awọn eeyan Togo finra, akọsilẹ ajọ IMF tiẹ sọ pe orilẹede naa lo tosi ju sikẹjọ lagbaye.
Awọn oludije alatako mẹfa ni yoo figa gbaga pẹlu Faure ninu ibi gbogbogbo ọjọ Abamẹta.












