Premier league fixtures:Atẹ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ sáà Premier League Gẹ̀ẹ́sí tó ń bọ ti jáde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu Tothenham ni opin ọsẹ tuntun ti yoo ṣide idije Premier League ti saa 2021 si 2022.
Idije naa yoo gberasọ ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, ti ẹgbẹ agbabọọlu tuntun Brentford yoo koju Arsenal fun igba akọkọ lati ọdun 1946-47.
Ẹgbẹ agbabọọlu Norwish ati Watford ti wọn ni ilọsiwaju ni saa to kọja yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ati Aston Villa.
- Israel Adesanya dúró sókè ténté nínú ìjàkadì UFC lẹ́yìn tó fẹ̀ṣẹ́ fọ́ Vettori lẹ́nu
- England fọ́ Croatia lẹ́nu ní Euro 2020, wo àwọn ohun tó ṣókùnkùn sí ọ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà
- Christian Eriksen, agbábọ́ọ̀lù Denmark tó dákú lórí pápá ti jí padà níléèwòsàn
- Wo ìdí tó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn
Bakan naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United yoo koju Leeds ni Old Trafford, nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu to gba Ife Ẹyẹ Champions League, Chelsea yoo koju Crystal Palace.
Egbe agbaboolu Manchester United ti Pep Guardiola n ṣe adari fun ni awọn eniyan n woye pe wọn yoo ṣiṣẹ kara-kara lati di Ife Ẹye Premier League wọn mu, amọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu Spurs, Norwich, Arsenal, Leicester,
Southampton, Chelsea ati Liverpool ti wọn yoo koju ni saa akọkọ idije naa yoo natan bi owo pẹlu wọn.
Ki idije saa ti ọdun 2020 si 2021 to pari ni awọn alaṣẹ Idije Premier League ti fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu laaye lati jẹ ki awọn ololufẹ wọn wa si papako iṣere lati wa gboriyin fun wọn lasiko ifẹsẹwọnsẹ.
Amọ ko i tii han si gbangba iye awọn ololufẹ ereboolu ti wọn yoo gba laaye lati wa si papakọ naa.Bi saa kini ifẹsẹwọnsẹ Idije Premier League yoo ṣe lọ niyii…Brentford vs ArsenalBurnley vs BrightonChelsea vs Crystal PalaceEverton vs SouthamptonLeicester City vs Wolverhampton












