Euro 2020: England fọ́ Croatia lẹ́nu ní Euro 2020, wo àwọn ohun tó ṣókùnkùn sí ọ nípa rìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Goolu kan lati ẹsẹ atamatase agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi, Raheem Sterling ni orilẹede England nilo lati fagba han Croatia ni ifẹsẹwọn wọn to waye loni nibi idije Euro 2020 to n lọ lọwọ.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta ni Kalving Phillips tẹ paasi si Sterling to si fi suuru gbee sile.
Amọṣa Kalving Phillips lo gba oriyin gẹgẹ bi agbabọọlu to tan bi oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu oniruuru bira to da.
- Christian Eriksen, agbábọ́ọ̀lù Denmark tó dákú lórí pápá ti jí padà níléèwòsàn
- Wo ìdí tó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn
- Ìdè ọjọ́ pípẹ́ ti já, Villarreal fi Man United ṣe àtẹ̀gùn dé ilẹ̀ ìlérí ní àṣekágbá Europa League
- Aston Villa fọ́ Chelsea lẹ́nu, àmọ́ Tottenham daṣọ àṣírí bò wọ́n
Ninu ọrọ rẹ, akọnimọsgba orilẹede England, Gareth Southgate ni inu oun dun pupọ fun bi awọn agbabọọlu oun ṣe ṣe daradara si ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. O ni lootọ yoo mu ẹru wiwo kuro lọrun awọn "ṣugbọn eyi ko tumọ si pe awọn ti pegede fun ipele to kan."
Nibayii, orilẹede Scotland lawọn agbabọọlu England yoo maa koju bayii.
Lọjọ Ẹti ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa iṣire Wembley.
Croatia ni tiwọn yoo maa koju Czeck Republic.
Kini awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ifẹsẹwọnsẹ naa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Igba akọkọ niyi ti orilẹede Gẹẹsi yoo maa bori ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Yuroopu, European Championships. Wọn ti gba mẹsan ṣaaju eyii, wọn ta ọmi marun un, wọn fidi rẹmi ni mẹrin.
- Fun igba akọkọ lati oṣu kẹta ọdun 2015, igba akọkọ niyi ti England yoo maa bori ni ifẹsẹwọnsẹ meje tẹlera.
- Raheem Sterling ti lọwọ ninu goolu mọkandinlogun ti England gba wọle awọn alatako rẹ. O ṣeranwọ fun goolu mẹfa, oun funrarẹ gba mẹtala sawọn.
- Jude Bellingham to wọle rọpe balogun iks orilẹede Gẹẹsi, Harry Kane di agbabọọlu to kere julọ ti yoo fi ẹsẹ kan bọọlu ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Yuroopu, European championships. Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati ojilelọọdunrun o le mẹsan ọjọ (17 years 349 days) ni loni.








