Christian Eriksen: Agbábọ́ọ̀lù Denmark, Christian Eriksen, tó dákú lórí pápá ti jí padà níléèwòsàn

Christian Eriksen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbabọọlu orilẹ€de Denmark, Christian Eriksen ti ji saye nileewosan lẹyin to dakun lori papa lasiko ti orilẹede Denmark ati Finland fi n figagbaga lọjọ Satide.

ṣaaju isinmi aarin ifẹsẹwọnsẹ naa ni wọn da a duro lẹyin ti agbabọọlu ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa to n gba bọọlu jẹun fun Inter Milan ṣa dede ṣubu lulẹ.

Kiakia ni alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, Anthony Taylor ti ke sawọn onimọ iṣegun ki wọn wa fun un ni itọju lori papa.

Ajọ ere bọọlu nilẹ Yuroopu, UEFA sun ifẹsẹwọnsẹ naa siwaju nitori iṣẹlẹ naa ki wọn to tun kede pe ifẹwọnsẹ ọhun yoo waye ni agogo meje abọ alẹ ọjọ Satide kan naa.

Iks agbabọọlu Finland ti fi atẹjade kan sita pe "Christian Eriksen ti laju, ilera rẹ si ti duro deede ti wọn si ni awọn n fi ọkan gbadura fun pe ki ara rẹ tete bọ sipo