Atiku Appeal: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yóò gbẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn PDP lọ́jọ́rùú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria ti da Ọjọru ọgbọn ọjọ oṣu Kẹwa to n bọ gẹgẹ bi ọjọ ti yoo gbẹjọ kotẹmilrun ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar n gbe bọwa lori idibo aarẹ 2019.
Igbẹjọ yi n waye lẹyin ti Atiku kọwe kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ti waye ṣaaju.
Ẹgbẹ oṣelu PDP lo kede ọrọ yi loju opo Twitter wọn ti wọn si ni ''asiko to bayi lati doola Naijiria''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá, omi máa ń bọ́ lójú mi tí mo bá rántí àkókò náà - Small Doctor
- Sola Sobowale gbàmì ẹ̀yẹ òṣèré tíátà obìnrin tó dáńtọ́ jùlọ
- Olóṣèlú tó nílé kiri, tó tún fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà, ẹ kò ní lọ láì pọ ohun tí ẹ jí - Tunde Bakare
- "Olóṣèlú ní Kogi àti Bayelsa ti ń pín Irẹ̀sì, iyọ̀ lásìkò ìpolongo ìbò, INEC, ẹ mú wọn"
Ẹgbẹ alatako naa ni awọn ṣetan lati tako esi idibo to gbe aarẹ Buhari wọle lọdun 2019.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu iwe kotẹmilọrun ti wọn fi ṣọwọ sile ẹjọ to ga julọ, wọn ni igbimọ igbẹjọ idibo naa ṣe aṣiṣe ninu idajọ wọn.
Bakan naa ni wọn sọ pe aarẹ Buhari ko sọ ootọ fun INEC nipa iwe ẹri rẹ to fi kalẹ.
- Kí ló ń lọ láàrin Tiwa Savage àti Wizkid?
- Ìgbà ọ̀tun dé! Ìjọ Àgùdà dìbò pé kí àwọn baálé ilé tó ní ìyàwó má a jẹ àlùfáà ìjọ
- Lizzy Anjorin yóò jàre Toyin Abraham tó bá jẹ́ pé wọ́n lọ sílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi
- Bí kò bá sí mítà ìgbàlódé Prepaid, a kò ní sanwó iná mọ́ - Ọmọ Nàíjíríà yarí
- Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mo ti ń bá Adẹ́rùpọkọ̀ ṣe eré tíátà - Tope Alabi
Loṣu kẹsan, igbimọ olugbẹjọ idibo fọwọ rọ ẹsun ti Atiku gbe wa si iwaju rẹ pe ko fi ẹsẹ mulẹ to.
Atiku ati ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn fẹ ki ile ẹjọ to ga julọ wọgile idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, ki wọn si kede Atiku gẹgẹ bi aarẹ.













