2019 Elections Update: Inec so ìkéde èsì ìbò ààré rọ̀ di aago mẹ́ta òru

Oríṣun àwòrán, InEC Twitter
Ajọ eleto idibo INEC ti ka esi ibo aarẹ ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu ilu Naijiria Abuja tan.
Ohun ti o ku bayii ni ki alaga ajọ Ọjọgbọn Mamood Yakubu kede ẹni to wọle ibo aarẹ ninu Atiku ati aarẹ Muhammadu Buhari.
Ẹwẹ, Ọjọgbọn Yakubu kede pe iṣẹ si pọ fawọn lati ṣe lori esi idibo aarẹ ọhun.
Lẹyin naa ni alaga ajọ INEC kede pe awọn fẹ lọ simi diẹ, o ni wa yoo tẹsiwaju laago mẹta orun Ọjọru.

Ẹwẹ, ẹgbẹ alako PDP ti sọ pe awọn ko ni gba esi idibo ti ajọ INEC kede lati igba ti wọn ti n ka esi ibo naa.
Buahari jawe olubori ni awọn ipinlẹ bi Kano, Katsina, Bauchi, Kaduna, Bornu, Yobe pẹlu ibo to pọ yanturu.
Bakan naa ni Atiku la Buhari fẹyin Buhari gbo lẹ lawọn ipinlẹ bi Adamawa, Benue, Cross River, Abia ati olu ilu Naijiria Abuja








