Ìmúra málegbàgbé ti Sẹnatọ Dino Melaye ti mú níle aṣòfin àgbà l'Abuja

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọja ní àtúndi ibo ilé ìgbìmọ àsọfin àgbà wáye láàrin Sẹnatọ Dino Melaye ti ẹgbẹ òṣèlú PDP àti Sẹnatọ Smart Adeyemi ti APC láti sóju ẹkun ìwọ̀-òòrun ìpínlẹ̀ Kogi.

Sùgbọ́n fún ìgbà keji Sẹnatọ Dino Melaye tun fidirẹmi.

Lásìkò tí Dino Melaye fi wà ni ilé ìgbìmọ̀ àṣòfin àgbà l'Abuja, oríṣiríṣi àṣọ àti ìmúra to pani lẹrin ló maa ń wọ wá si ìjòkó ilé.

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @Dino

Àkọlé àwòrán, Dino Melaye rèé lẹ́yìn ti ó jábọ nínú mọto ọlọpàá
Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @Dino

Àkọlé àwòrán, Sẹnatọ Dino Melaye nínú ilé aṣòfin, O kuku mura bii ti àwọn eniyan ilẹ̀ Arewa (Hausa)
Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @Dino Melaye

Àkọlé àwòrán, Sẹnatọ Dino Melaye wọ aṣọ ìkẹ́kọọ gboye jáde wa si ipade ile igbimọ aṣofin, lásìkò tí wọ́n ni ko gboye jade fasiti
Dino

Oríṣun àwòrán, @Dino Melaye

Àkọlé àwòrán, Sẹnatọ Melaye ló tun ju ẹ̀gbà ọrun ti awọn kan ṣapejuwe pe "O make sense" lori ayelujara lọ si ilé aṣòfin
Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @Dino

Àkọlé àwòrán, Ìmúra Dino Melaye tun rèé bi Báàlẹ ìlú tabi alade ti ko fẹ mura tan pẹlu irukẹrẹ lọwọ
Dino ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, @Dino

Àkọlé àwòrán, Nínú ilé ìgbìmọ asòfin, àwọn ènìyàn máa n ri Dino Melaye àti Ademola Adeleke bii Amuludun, Bi ẹnikan ṣe jẹ olórin, bẹ́ẹ̀ ni ẹni kan jẹ oníjó
Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @Dino

Àkọlé àwòrán, Àwọn ǹkan málegbàgbé ti Dino Melaye ti ṣe níle aṣòfin àgbà
Àkọlé fídíò, FUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA