Burkina Faso attack: Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́rinlá lásìkò ìjọsìn

Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́rinlá lásìkò ìjọ́sìn

Awọn agbebọn da ibọn bolẹ nile ijọsin onigbagbọ kan ni orilẹ-ede Burkina Faso.

Iroyin naa ni awọn obinrin ni wọn n ṣe ipade adura lọwọ nile ijọsin naa ni ana ọjọ Aiku ni ila oorun Hantoukoura.

Titi di asiko yii, ko sẹni to le sọ nipa awọn oniṣẹ ibi to huwa buruku yii.

Atejade ti ijọba ibilẹ naa fi sita ni ọpọlọpọ awọn eniyan lo farapa nibi iṣẹlẹ naa.

Ijọba Burkina Faso ni oun ko le ṣo nipato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ibi yii.

Agbofinro kan ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ fun akọroyin AFP pe awọn agbebọn lo ṣe iwa ika yii.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Iroyin naa ni wọn tun yinbọn lu oluṣọaguntan ṣoṣoọṣi naa atawọn ọmọ wẹwẹ to wa nibẹ.

Loṣu kẹwaa ni awọn agbebọn kọlu awọn kan ni mọṣalaṣi ni eyi ti awọn meẹdogun doku.

Lati ọdun 2015 ni ikọlu sile ijọsin ti bẹrẹ ni orilẹ-ede Burkina Faso ni eyi to ti mu ki awọn alaṣẹ ti ọpọlọpọ ile iwe pa.