Mali: O kéré tán, ẹ̀mí 95 ti sọnù ní Mali

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eniyan mọkandinlogun tun ti dawati ni Mali.
Ijọba orilẹ-ede Mali ti ke gbajare fun gbogbo agbaye lori ikọlu to n ṣẹlẹ ni ẹkun Mpoti.
Ikọlu awọn alakatakiti ẹsin Islam ti wọn n pe ni Al Qaeda ati Islamic State Group ti n wọpọ sii ni Mali bayii.
Akọroyin BBC to wa nibẹ ni wọn dana sun ilu naa ni ti ọpọ ẹmi ati dukia si ti sọnu.
Ijọba ilẹ Mali ni iṣẹlẹ ibi yii ko ṣeyin awọn agbesunmọmi ṣugbọn awọn ara agbegbe naa n kigbe pe awọn Fulani lo wa nidi ọrọ naa.
Ajọ ipese alaafia ninu ajọ Iṣọkan Agbaye, United Nations ti kede pe oun ti gbe igbeṣẹ lati dẹkun iwa ibi yii.
UN ni wọn ti fi awọn ọmọ ogun ranṣẹ si ẹkun yii ki iru ikọlu yii ma tun le waye mọ.
Ajọ UN ni oun tun ti fi awọn oluwadii nipa ẹtọ ọmọniyan ranṣẹ sijọba Mali ki wọn le pese iranlọwọ fun ijọba Mali ninu iwadii ti wọn n ṣe.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Lojiji ni awọn agbebọn kan ya wọ ilu Dongon ti wọn si fi ọpọ ẹmi ṣòfò.
Ó kéré tán, ẹ̀mí 95 ti sọnù nínú ìkọlù Fulani ní Mali
Agbegbe Sobane-Kou nitosi Sanga ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ni aarin gbungubn orilẹ-ede Mali.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye fun BBC pé awọn oniṣẹ ibi yii tun jo ọpọlọpọ ilé ni ina.
Oṣiṣẹ eleto aabo abẹlẹ kan ṣalaye fun BBC pe, niṣe ni wọn n sun awọn eniyan naa lẹyin ti wọn pa wọn tan.
O ni oun ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ninu awọn oku ti wọn ti ri yọ sita.
Ogun ẹlẹyamẹya ti maa n figba gbogbo ṣẹlẹ laarin awọn Fulani ati awọn eniyan ẹya Dongon ni aarin gbungbun Mali tipẹ.
Opọ igba ni wọn maa n fẹsun kan ara wọn pé wọn n ji ẹran ọsin ara wọn ko.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹta, ọdun ni wọn ni o kere tan ọgọjọ awọn jagunjagun ni aja awọn ọlọdẹ pa ni agbegbe Ogossagou to sunmọ Burkina Faso.
Yatọ si ija ẹlẹyamẹya to n ṣẹlẹ leralera, lati ọdun 2012 ni wọn ti bẹrẹ ija ẹsin to ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ.
Awọn Fulani ti wọn jẹ alakatakiti ẹsin Islam ati awọn ti ko gba ẹsin kankan gbọ ni wọn n fẹsun ikọlu yii kan julọ.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan awọn agbebọn kan ni Dongon ti wọn n pè ni "Dan Na Ambassagou'.
Wọn tun ni ko le ṣẹyin awọn agbesunmọmi ni ẹkun yii.
Ijọba Mali ti gbogun ti awọn ẹgbẹ "Dan Na Ambassagou' lẹyin ikọlu Ogossagou.

















