Femi Fani Kayode: Ọ yẹ kí wọ́n jó Fairstein ní iná ni

fani kayode

Oríṣun àwòrán, @Femi Fani Kayode

Àkọlé àwòrán, Linda jẹ ẹlẹyamẹya to jẹ ọmọ ijọ Satani
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ki n má purọ, ọmọ ijọ Satani ní Linda Fairstein -Femi Fani Kayode.

Femi Fani Kayọde to ti figbakan jẹ minista fun ọrọ ọkọ ofurufu ni Naijiria loun àti awọn ọmọ ìjọ Satani ti n tahun sira wọn lori ayelujara.

Femi Fani Kayode bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa ti agbofinro New York lorilẹ-ede America tẹlẹ, Lindsay Fairstein hu.

Fairstein ni aṣaaju olupẹjọ ọrọ ifipabanilopọ to ṣẹlẹ ninu ẹjọ Central Park Five ni New York.

Femi ni iwa aida to ba irinajo ọjọ iwaju awọn ọdọ marun un jẹ ni ọlọpaa tẹlẹ yii hu.

Àkọlé fídíò, FFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Awọn ọdọ ọmọ African-American mẹrin ati Hispanic kan ni wọn ṣe aṣiṣe fẹsun kan ti wọn si ran sẹwọn lọdun 1989.

Wọn ni àwọn maraarun fipa kọlu obinrin alawọ funfun kan to n sare idaraya ni agbegbe Central Park.

Ninu ọrọ Femi Fani Kayode lo ti ni ọmọ ijọ Satani ni Linda yii jẹ fun iwa idẹyẹsi to hu sawọn ọdọ ti kii ṣe alawọ funfun yii.

Kete ti Fani Kayode sọrọ yii naa ni awọn ọmọ ijọ church of Satan ti bẹrẹ sini fun un ni esi pe ki o má fi ọrọ ti awọn sii:

Ni ọrọ ba di dámi lohun ki emi naa fún é lesi pada.

Àkọlé fídíò, Aborisade: Mẹ̀kúnù gbọ́dọ̀ funra sí Obasanjo

Ta ni Fairstein Linda yii?

Linda Fairstein jẹ onkọwe ọmọ ilẹ̀ Amẹrika.

O ti figba kan jẹ amofin to n mojuto ọrọ igbogunti iwa ipa si awọn ọmọde ati obinrin ni ẹkun Manhattan ni New York ni Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

Linda ṣiṣẹ gẹgẹ bii adari ẹka ẹsun ibalopọ laarin ọdun 1976 si ọdun 2002.

Ni asiko yii ni iṣẹlẹ ẹsun ifipabanilopọ awọn ọd\ọkunrin marun un naa ṣẹlẹ lọdun 1989 ni central Park

Lọdun 2002 ni Matias Reyes, to jẹ ẹni ti wọn mọ ni afipabanilopọ to tun jẹ apaayan jẹwọ pe oun loun ṣe iṣẹ buruku yii.

Atọ ọmọkunrin Reyes, ati ẹjẹ rẹ ba eyi ti wọn ri lara obinrin alawọ funfun naa mu ni eyi ti wọn fi fidi otitọ mulẹ.

Sibẹ, Fairstein ṣi sọ pe ọwọ awọn ọdọmọkunrin ti wọn sẹ aṣiṣẹ fẹsun ifipabanilopọ naa kan ko mọ.

O dẹ gboriyin fun iṣẹ iwadii awọn agbofinro to mu awọn ọdọmọkunrin alawọ dudu wọnyii.

Àkọlé fídíò, #Sweetsweetcodeine: Ẹ wo bí ìròyìn BBC nípa oògùn ikọ́ Codeine ṣe ń tún ayé tó ti bàjẹ́ ṣe