Gómìnà Makinde fẹ́ dá àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ sílẹ̀ l'Oyo

SEYI MAKINDE

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Kano wa lara awọn ipinlẹ to wa lara awọn ipinlẹ to ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni ipinlẹ naa.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti fi ipinnu rẹ han lati da ajọ silẹ ti yoo ma a gbogun ti iwa ibajẹ ni ipinlẹ naa.

Gomina Makinde sọ eyi lasiko ti wọn n se ibura wọle fun awọn aṣofin ipinlẹ ti wọn dibo yan si Ile Igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

O ni ijọba oun ṣe tan lati gbogun ti iwa ibajẹ, nitorina ni awọn yoo ṣe rii daju wi pe awọn gbe abadofin jade ti yoo se ifilọlẹ ile-iṣẹ ijọba ipinlẹ ti yoo maa gbogun ti iwa ibajẹ.

Agbẹnusọ fun gomina naa, Taiwo Adisa fi kun un wi pe gomina Makinde ṣe tan lati jẹjọ ti ajọ naa ba ri i wi pe oun ru ofin iwa ibajẹ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ sii: