FIRS: Ijọba Nàìjíría ṣetan láti bẹ̀rẹ̀ si ni gbowó orí lóri ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Muhammadu Buhari n gba ipe lori aago

Álága ilé iṣẹ́ tón gbowo orí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (FIRS), Babatunde Fowler tií ni báyìí o, ko si ǹkan to buru ninu kí ìjọba máá gba owo orí fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lori ẹ̀rọ.

Fowler sọ èyí di mímọ lásìkò tó n ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àpérò ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà tó wáye nilu Abuja.

"Ẹ jẹ́ kí n sọ báyìí, Ọmọ Nàìjíríà máa ń sọ̀rọ̀ púpọ̀ jùlọ, wọn a maa sọ̀rọ̀ ju bo ṣe yẹ ki wọ́n sọ̀rọ̀ lọ, ẹni to ba si lágbàra láti sọ̀rọ̀ to bi wọ́n ṣe ń sọ yìí tí a bá gbé owo ori lee, ko sí ǹkan to buru níbẹ̀"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A máa fi ara wa we àwọn orilẹ̀-ède to ti tó tán, sùgbọ́n ìdá méji ninu ìdá ọgọ́rùn ni Ghana ń gba lówó orí fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀, wọ́n si maa n lo ǹkan ti wọn ba ri níbẹ̀ láti gba bùkáta àwọn fásìtì wọ́n, èyí si lo mu ki àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ maa kawe ni Ghana."

Fowler
Àkọlé àwòrán, Ọmọ Nàìjíríà ti le sọ̀rọ̀ jù, A o fi owo orí kún ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Ní báyìí àwọn asòfin n pète ìdá mẹsàn fún owó ori ibaraẹni sọ̀rọ̀ láti fi rọ́pò ida meji owo ti ìjọba gbe lé ọjà rírà láìpẹ́ yìí.

Fowler tún sàlàye lóri owó ori ti wan fi le ọjà rírà lori ayélujara pé gbogbo àwọn ti wan ń lo ayelujara láti ta ọjà wọ́n ni àwọn banki yóò ti maa yọ ìdámarun ninu ǹkan ti wọ́n ba ta, láti fi sọ̀wọ si FIRS.