Anthony Joshua: Ta ni yóò borí nínú abala kejì ìjà Ruiz pẹ̀lú AJ?

Andy Ruiz Jr ati Anthony Joshua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹ ku oju lọna abala keji ẹṣẹ kikan laarin abẹṣẹkubiojo, Anthony Joshua ati alatako rẹ, Andy Ruiz to fẹṣẹ dara si i lara niluu New York lorilẹede Amẹrika.

Onigbọwọ Joshua, Eddie Hearn ti kede pe ninu oṣu kọkanla tabi ekejila ni atunja ija naa yoo waye laarin awọn mejeeji.

Ruiz di ọmọ orilẹede Mexico akọkọ ti yoo aṣaaju ninu awọn agbaọjẹ akẹṣẹ lagbaye lẹyin to na Joshua bi aṣọ ofi to si gba igbanu mẹta ti Joshua ko wa.

Ọjọ Iṣẹgun ni Ọgbẹni Hearn ṣalaye loju opo Twitter rẹ awọn yoo kede ibi ti ija naa yoo ti waye laipẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹmẹrin ọtọọtọ ni Joshua ṣubu ṣere ko to gba pe Ruiz lọga nigba ti ija de ipele keje ti Ruiz si gba igbanu mẹta ti Joshua gbe wa.

Hearn fikun ọrọ rẹ pe o ti di dandan fun Joshua lati gbẹsan bayii nigba ti awọn mejeeji ba koju ara wọn fun igba keji ninu oṣu kọkanla tabi ekejila

Irọ́ ńlá! Ẹ̀rù kò ba odò Joshua, ojora kò mu, kó tó ríyà he lọ́wọ́ Ruiz

Ko si otitọ kankan ninu ọrọ to n tan kalẹ lori ayelujara pe, Abẹṣẹkuojo, Anthony Joshua ni ipaya ọkan tawọn oloyinbo n pe ni ''panic attack'', ki o to kọ lẹta si iya lọwọ Andy Ruiz lopin osẹ to ja.

Anthony Joshua ati Andy Ruiz

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iya jẹ Anthony Joshua l'Amẹrika

Eddie Hearn to jẹ onigbọwọ Joshua lo sọ bẹẹ. Hearn sọ pe, koko lara Joshua le ko to ba Ruiz ja.

Eddie Hearn

Oríṣun àwòrán, Twitter/Eddie Heran

Àkọlé àwòrán, Ija Anthony Joshua ati Eddie Heaen

Ọpọ lo n sọ lori ayelujara pe, o dabi ẹni pe ooyi n kọ Joshua nigba ti ija naa n lọ lọwọ, eyi to ṣokunfa bi o ti fidi rẹmi ninu ọja ọhun.

Koda, awọn kan sọ pe Joshua fẹ ki wọn sun ija oun ati Ruiz siwaju, ki ija naa to bẹrẹ nitori bi ara rẹ ṣe ri.

Joshua lo fa baba rẹ sẹyin nigba ti o fẹ lọ koju onigbọwọ rẹ, Hearn lẹyin ti ija pari.

Andy Ruiz

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idunu ṣubu layọ fun Andy Ruiz

Gbogbo rẹ daru mọ Joshua loju ninu ija ọhun debi wi pe, o n beere lọwọ olukọ rẹ pe ki lo de ti ara oun fi n ṣe bakan, ati pe, nigba wo nija naa yoo pari lẹyin ti Ruiz rọjo ẹṣẹ le lori.

Joshua, ti awọn oniṣegun gba nimọran pe ko sinmi nile di Ọjọru, ti fagile isinmi ọlọjọ mẹwaa to fẹ ṣe tẹlẹ l'Amẹrika, ko le tete pada silu London.

Ṣugbọn o, ju gbogbo rẹ lọ, Joshua ko ni awawi kankan fun ijakulẹ rẹ, bakan naa lo sọ pe, oun ko foju kere Ruiz.

Ninu oṣu Kọkanla tabi Ikejila ọdun 2019, ni Joshua ati Ruiz yoo tun ija naa ja nilẹ Gẹeṣi.